Smiley face

Lẹta igbe aye mi ati ero okan mi

Agbara Ogo Ilẹ Adulawọ
Mo tun de bi ìse mi. Laise alabahun, ọrọ mi lo kun gbogbo igboro ayelujarabiajere. Ojuti gan-an lo jẹ fun mi pelu ọjọ ori mi wi pe, bi n ba fẹ jẹun, a fi ki n pada sibi won ti gbe womi dagba. Gbogbo awon ẹni a jọ dagba ni won ti gbe ohun rere se. Ọgbẹ ọkàn lo jẹ fun mi ti mo ba wo igbe aye awon ẹgbẹ mi, ti mo tu wa boju wo igbe aye temi n gbe.



Otito lọrọ awon agba wi pe, inu abimọku ki i dun. Ko sọmọ ti baba o pitan ọlà fun ninu ìsẹ́ ti ko ni bọkàn jẹ. Kosi ẹda eniyan ti o wu ko jẹ ẹru. Iru iyanju wo la fẹ gba ẹni ẹkùn paya ẹ jẹ. Bi ewure ba boju weyin, o le fepe ranse fẹni epe tọsi. Amọ, mo ti se ileri wi pe, mi o ni sepe, enu mi o si ni gbofo.

Ni o ya opolopo yin lenu wi pe mo le tẹ iru ọrọ bayii jade.

Amọ ki ni kan lo damiloju, bi eniyan ko ba to ọkan to wa n pe ara rẹ ni meji. Bi igba ti iru ẹni bẹẹ sun ẹlẹya rẹ siwaju lo jọ loju temi. Ika ti o ba si n dun ni, a ki i fi bọ abẹ aso. A ti wi pe, bi eniyan ba n sare koju ma ti oun, ti oju ba ti tini, aré ka ma ku lo ku.

E maa je n tan yin, ti mo ba ni ko su mi iro ni mo pa. E je ka dupe lowo aso to padi mọ. Omo elomii i ba bọra sile ko ba jọbọ, omo elomii le bora ko jòwè. Atike funfun ti mo fi n raju ni ko je kẹẹ mo wi pe mo ti dagbada booru gbigbona mabẹ.

Didaloda lomo fi degbe, egbe ki i sele omo. Eni ija kosi de ba lo n pe ara re lokunrin. Òjò lode lapẹrẹ mi dohun apati. Taikawe ko, bi mi ò tilẹ gbe sabuke mi lori, gbogbo yin le mo wi pe odun gbooro ni mo fi kosemose gidi. Bẹẹ, emi o si fari apakan da apakan si, bi mo se kogbon iwe ni mo tun kose owo to yanranti. Sebi won ni atelewo eni ki i tannin je.

Ori mi sipe bi alajo Somolu. Abi eyin o ti gbotan alajo Somolu ri? Bee ebun ti oba Adaniwaye kosi inu mi ko se fenu royin tan.

Asodun ko, won ni sunmoni la a mose eni. Eni to ba bami lo lo le royin. Bi won tile n pe mi lẹgbọn, sugbon awon agba ni bi a ko ni nnkan agba, bi ewe laari.

Aseyori awon aburo leyin mi ko tile je ki n le fọwọ soya wi pe emi lẹgbon mọ.

Ẹkun lo n daamu Ọloruntoowo emi naa o, Oloruntoowo ki i se ajakaja. Kosi eni ti won gbe gori
esin ti o ni so ipako seyin. Eniyan ti ko si jeun kanu kii ja gidigbo.


Eyin e kan gbiyanju ke e fun mi lọ́kọ́ gidi to se e roko, ẹ si fun mi nílẹ̀ olora to se e kobe. Mo fi dayin loju wi pe, agbẹ mi o yan fanda, maa si dabira koja kereemi. Abi e se boya mi o le roko ni? Koda, mo le da ẹmu lori ọpẹ.

Oju lo pe si, akololo mi o pada pe baba. E fun mi gègé ikowe pelu takada funfun. Agberugbesọ kọ, ọpọlọ pipe mbe latari mi. Bee ba fun Igbira mi lotin yoo feebo. Igberaga ni wi pe mo ti mọ kọja ẹkọ kikọ, mi o si bikita ki n tun gbogbo ẹkọ mi kọ lati ibẹrẹ dopin leekan sii.


E maa jẹ ki n tan yin, akinkanju akoni ni mi. Akọ okuta ni mo fi n se irọri sun lale. Ibi to si le kokoko ni won ba okunrin mi. Sugbon awon ti won sin esisin ni won ko fe ki egbo mi o jina bọrọ.

Won ni bo ba jina kini keesin awon o maa ri je? Bee egbo adaajina ko je ki n le se bo ti wu mi lawujo.

Agbara ni mi e maa foju olosi wo mi mo. Kosi eni to subu ti n rerin. Eni o lori lori n fọ. Inu abimọ ku kan ki i dun.Omo abule sowo ni mi, awon amọkoko ni won so gbogbo ilẹ damọ. Mo tun dọgbọn ki n bu amọ mọ ladugbo. Ọjọ ti mo fẹ lo fi ladugbo ponmi lodo ni ilẹ amọ tun yọ mi, ladugbo tun se bẹẹ gborun lọ.

Sibẹsibẹ, igbagbọ mi ko ye. Emi ni Kutanti okunrin ogun!

Igbagbo mi le kokoko bi ota. Mo si n wo ọjọ ọla pelu ireti nla. Leyin okunkun, imole nbo. Mi o ni je ko su mi, mi o si ni je ko remi. Bi ekun pe titi dale, ayo nbo lowuro. Òòlù lusọ titi bi kasọ o faya, sugbon kaka ki asọ faya, didan ni i dan gbirin bi idẹ.

E ma so ireti yin nu ninu mi. Ireti ati igbagbo yin lo le mu mi duro. Ẹ ri daju wi pe ẹ kọ awon omo yin ni agbara ọrọ ati ireti. Ki won ma si oro odi mọ, ki won si ma so ireti nu ninu mi.

E so di asa yin, e si so di akomona yin, e je ki igbagbo ati ireti maa jade ninu itakuroso yin. E ma dekun adura fun awon ti won dari mi. E si ri daju lati se ojuse yin gege bi o ti ye fun ogo ati igbega mi. Ki Oluwa bukun mi.

Emi ni ti yin ni tooto,
Naijiria, Ilu Ogo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment