[Jack Bauer ati Tony Almelda tẹsẹ duro diẹ, won n wòye. Bẹẹ Jack Bauer n sọrọ lọ lórí foonu pelu Chloe lati yara agbara ni CTU]
Jack Bauer: Chloe, Ati n wole lọ.
Ọrọ ori foonu pelu Chloe]: Ẹrọ ayaworan kan bẹ lẹnu ọna to jade soke. Mo le daro lọwọ iṣẹ fun isẹju àáyá marun-un, ẹ gbiyanju kẹẹ súré kọja ti ina pupo ba ti sẹju belebele, bi ẹ ko ba se bẹẹ wọn o ri pe ẹ ti n bọ o.
![]() |
Chloe n juwe ona fun Jack Bauer lari eka CTU |
Jack Bauer: Kọpi èyun-un.
[kete ti ina pupa ọun sẹju lébélébé Jack Bauer ati Tony Almelda súré kọja, wọn tun jáde sẹẹdẹ gigun kan gbọọna]
Ọrọ ori foonu: Yara kẹta lẹgbẹ ọtun ibẹ ni won wa.
Jack Bauer: Kọpi èyun-un.
[Jack Bauer ati Tony Almelda jọ n tiro ẹsẹ bi wọn se n sunmọ yara ti Chloe n juwe fun won. Ìgbà won de ẹnu ọna ọun, wọn pin ra wọn síhìn-ín sọhun-un lẹnu ọna bẹẹ ni won fọwọ ba ara wọn sọrọ]
Jack Bauer: Eni… eji… ẹta a a a
[Ori ẹlẹẹkẹta ni awon mejeeji dijo fi ipa ja ilẹkun wọle lojiji. Kété tí won wọle lawon ti mbe ninu yara ta kiji ti won si n sure gbebon soke]
Jack Bauer: Oóko mi Jack Bauer. Ati ẹka ti n dìgbòlù awọn ẹgbẹ agbésùnmọmí ni mo ti wa. O ya, ẹju ibọn ọwọ yin le kẹ ẹ kawọ yin sóke.
Etí yin di ni abi ẹ fẹ ki Ogun fẹjẹ yin wẹ ni? O da mi loju wi pe ẹni fẹ fi koste se gọgu, ko si ni wuyin kẹ jeun l’Agugu kẹ sanwọ s’Adeọyọ, ẹyin gan-an ò ni fẹ fi transformer se pillow, ẹyin ba wo? E ni fẹ fẹyinti lori okada men. Nigba ti ori yin o buru mọ tilẹ. Owo yin loke kin to yin yin ni bajinatu. Ẹ yin kẹ, fiimu to gun gan, ẹ kẹdẹ ni woo tan. Season three ta jọ bẹẹrẹ yii ẹni act ẹ tan.
[Jack Bauer tun sọrọ lori foonu pelu Chloe] Chloe, O seun! Owo ti tẹ awon were oun.
0 comments:
Post a Comment