Olorun Erujeje
Oluwa Ọlọrun ẹrujẹjẹ.
'Èmi ni' lorukọ ti Ìwọ njẹ.
Agbé ọ ga nítorí ẹni ti ìwọ jẹ.
Mo wo òréré ayé kòsí ẹni le sàlàyé ẹni ti Ìwọ jẹ.
Bi mo tilẹ gunyan nínú odó Ìwọ ò ni jẹ.
Ọpẹ́ mi rè é gẹ́gẹ́ bi ẹ̀jẹ́ ti mo jẹ́.
Mo dupe nitori O kò jẹ ki ẹyẹ ayé pa mi jẹ.
Bi awon ota tile pejo lati ba mi je.
Igbagbo mi duro ninu oba ajagun segun aidibaje.
Olayemi Dakewi mo jẹjẹ.
Ko si ohun kankan laye yii ti mo le jẹ.
Gbogbo igba ni ma jewo re gege bi Ọlọrun Ẹrujẹjẹ.
0 comments:
Post a Comment