Smiley face

Baba Orobo Ti Yi Ero Re Pada

Manny Yarbrough ti Guinness Book of Records kede gege bi elere idaraya to tewon ju lo (to wuwo ju lo) ti setan ati jo bayii.

Okunrin onijakadi yii ni ara titobi ti su oun, oun fe jo die.

Lori meetmannyy.com to je ero ayelukara okunrin yii, ibe lo ti fi aidunnu re han nipa egbin to de ba a nigba to fe rin irina ajo lo si ilu Itali sugbon ti awon alase irinna ofurufu ilu naa ko lati je ko wo inu baalu latari titobi re.

Won ni eru nla ni okunrin naa eleyii to seese ko ja baalu wale.

Bi o tile je wi pe tikeeti aga meta ni okunrin yii ra fun oun nikan lati joko si, sibesibe won ni ko saaye fun un.

Awon nnkan ti Manny ro papo ni yii to fi ni ara sisan ti su oun.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment