![]() |
Ojogbon Akinwumi Isola |
Ko si idi kankan ti a fi le so wi pe awon oluko wa ko gbiyanju to, bi o tile je wi pe eto eko Naijeria pofo bi iyo to da sinu erupe ile. Awon Yoruba si bo, won ni ika to ba se ni oba n ge. Ti omo eni ba si pegede ki lo buru ninu ka ko oropotoyun baba awon ileke sidi iru omo bee. Ni iwon igba ti o ba ti je wi pe ti oju ba ti n sepin a fi n han oju ni, ki lo wa buru ninu ka gbe ade fun esin funfun to mu ori dele? Ki lo ‘baadi’ ninu ka dupe lowo babalawo to koni n’Ifa ori ire? E je ka ki tisa to komo niwe to ye omo yekeyeke, nitori tisa to ya olodo ko le fi ogbon ro omo lara bi aso.
Eko to je ojulowo to gba arogun
tabi arojinle ise opolo ti n soni doosa ojiji, agbekale atotonu to ridi joko bi
igi araba nla pelu ise iwadii to duro soke tente bi Olumo ti ko re jabo, igbelaruge ogbon atinuda eleyii to tayo takada
lasan, ogangan ibi ti ogbon ti domugo ti omugo tun yira pada dogbon lowo onise
alakada ti n yooru gbigbona. Olayemi, ko si igba ti mi o ni pada si Ifafiti.
Nibi ti Ifa fi ogbon ti si, ogangan ibi
awon onise alakada ti gbe n se ogbon bi igba adelebo n se egusi pelu irorun.
Bi o tile je wi pe kini kan pere lo
ba Ajao je, apa re gun bi opo ina monamona, itan re si ri gbonda bi omorogun amala.
Eto isakoso Naijeria ti je ki akurete de ba eto eko ile wa. Ohun to ye ko je
koko ti wa ni koko lori, ibadi aran oge to ye ko je ohun iwuri ti di yeyenatu.
![]() |
Awon Omo Egbe ASUU N Be Ijoba |
Sibesibe, kini mo le je gbagbe
kilaasi Imo Eda Ede mi?
Nibi ti awon onimo ti gbe n fi
iwadii tako ara awon pelu akawe to moyan lori. Awon kan ni n se ni a da ede mo
wa, iwadii awon onimo mii tun so wi pe igba ti a de ile aye ni a ko ede, gbogbo
won pata ni abere iwadii won si lokun nidi. Eleyii to nira fun wa lati ko ifa
enikeni danu ninu won.
Lopolopo igba lo je wi pe kilaasi
maa n pari nipa yiyi omugo pada si ogbon tabi ohun ti a ti gba gege bi ogbon
yoo si di eru akitan nipa agbeyewo awon ‘Oga Nla’ ninu ijinle ise opolo to daduro bi okiti ogan.
Kini Imo Eda Ede?
Lede kukuru, imo Eda Ede(Linguistics)
je orisii imo kan ti n se ofintoto bi ede se wa saye, tabi bi ase da ede.
Gege bi agbekale awon onimo Linguistiiki
se so, opolopo won gba wi pe ohun elemi tabi abemi ni ede je, eleyii to je wi
pe gbogbo igba lo n dagba sii. Eleyii si wa lara ohun ti o mu orisii imo naa
gun gbon-onna bi owo aso.
Joojumo ni ede n dagba awon ede
tuntun si n jeyo bi igbe aye iran omoniyan se n tesiwaju. Idi ni yii ti a fi ni
awon ede atijo ati ede tuntun.
Orisii ede tuntun yii le je agbelero,
ayalo ede lati inu ede mii, tabi awon ede ti olaju fi le wa lowo latari igba to
de ba wa.
Nikete ti ede tuntun ba ti jewo
tabi ti isele tuntun ba ti waye yala ni eka Imo Sayensi tabi Imo Ero, ojuse
awon onimo Eda Ede (nibayii, mo ti n so nipa awon onimo eda ede Yoruba nipato)ni
lati se atunse si ede ki iru emi ede bee le tesiwaju (se e ranti wi pe mo ni
ohun elemi ni ede je?).
Awon onimo ede Yoruba si n gbiyanju, sebi okunrin ti n
sun rara fun okunrin ni, ise ako nla ni iru won n se. Gbogbo igba ti awon ede
tuntun bee ba si ti n jeyo lagbaye, paapa ju lo leka Imo Ero ati Eto Ilera ni
atunse maa n de ba awon Ede Iperi (Metalanguage) wa fun atunse ilo ede to peye.
Nibayi, ohun kan ti gbajugbaja ni
ilu India. Ohun to gbajugba naa ni asa A-bani-bi-omo. Eyi ni wi pe toko-taya le
gbe ise oyun nini ati omo bibi fun obiriin ajoji. Leyin ti won ba bi omo naa
tan toko-taya yoo gba omo won pada lori adehun si ni, eleyii ti opolopo re si
maa n da lori owo. Opolopo awon eniyan kaakiri agbaye ni won n ti n lo si ilu
india la ti lo gbe ise oyun nini fun awon obirin ti won fi n se ise sise ni ilu
India. Pupo ninu awon onibara awon obirin yii ni won je awon okunrin meji ti
won n fe ara won laye ode oni gege bi toko-taya.
Nipase olaju ati idagbasoke ti o ti
de ba Eto Ilera ati Imo Isegun Oyinbo, awon dokita le gba ato okunrin ati
obirin ki won si ko sinu obirin ajoji ti iru ato bee yoo si pada doyun ati omo.
Iru igbese bayii ni won pe ni ‘Surrogacy’.
Surrogacy ati opolopo orisiirisii
awon oro tuntun mii ninu ede geesi lo ti di egungun eja si awon ojogbon lorun
nipa wi pe iru oro wo la le fi ropo re ninu ede Yoruba.
Olayemi Oniroyin, bi o tile je wi
pe mi o ni pe danu duro na, sugbon o hun to daju ni wi pe alaye mi si n bo
leyin bi eegun nla ti n dun yunmuyunmu bi olu-igbo. Amo kini kan lo da mi loju
saka, niwon igba ti ede kan ba ti duro lati dagba soke tabi lati gbooro nipa bi
awon ede yoku lagbaye se n tesiwaju nipase olaju, iru ede bee ki pe wole bi
Sango oko Oya.
E ku ikale.
O ga ooooo. Oriisirisii lo n sele ni ile aye yii. Ti opin aye ba ti de, orisirisi lao maa ri.
ReplyDelete@Olayemi oniroyin, e lo wa ni awon obirin yii n gba fun ise abaniloyun ti won se?
ReplyDelete@Nifemi, ni ilu india nnkan bi $20,000 ni won ni won gba. won maa n se iru e ni USA na, nnkan bi $50,000 lowo to kere ju t won ni won gba ni be. Aimoye ilu naa nii won ti bere iru ise naa sugbon ti ilu india gaayata gan-an awon eniyan de maa n lo si ibe daada.
ReplyDeleteSe abaniloyun ni itunmo surrogacy bayii ninu ede Yoruba? ati wwi pe lotito ni wi pe aimoye ede geesi lo wa ti won ko ti ba wa tu si edeYoruba. nini iru awon eda iru awoon ede yiii nii ede Ede yoruba yoo tunbo je ki ede Yorba niyi kari gbogbo agbaye. ede yoruba yoo si je ohun tose lo lawujo nibikibi
ReplyDeleteOtito le so, b io tile je wi pe adiye n laagun, sugbon iye ni ko je ka mo. Omi lo po joka lo. E se fun awon iriwisi yin
ReplyDelete@Olayemi, O se o. Ba wa ki won wi pe aje a maa wa oooo. LOL
ReplyDelete@Nifemi, awon ti n gbo ooo. Ti eyin naa ba de nife si iru bisineesi naa e le gbeyewo ooo. A bi eri wi pe owo goboi sibe ni? Erkk
ReplyDeleteA nation can not develop beyond the standard of her educational standard. If we ought to grow as a nation, the quality of our Education must be improved. Until we put the first thing first, our social life, economy, culture and tradition will forever stay behind stage while rest of the world take d whole stage. Olayemi Oniroyin, well done. Bye.
ReplyDeleteThanks
ReplyDelete