Smiley face

Soja Fi Aburo Iku han Oga Ade Ni Ikorodu


Ori taa ti ko iya mo ni ko ni salai je iya re gege bi a se kowe re kale. Okunrin kan lo ko sowo soja ni Ikorodu nigba to fo oju popona masose nibi to ye ko ti gba ori afara koja.

Ibeere kan pere ni soja beere lowo oga Ade, ti oga Ade si se bee gbegbagi.

'Se babalawo lo difa fun o wi pe ko maa gun ori afara koja ni abi iwo lo le shingoomu moju?'
 
Ibeere ti soja beere re lowo oga Ade lesi oro ba pakaso. Soja ba ni ki oga Ade na felefele, igba to na felefele ni won ni ko kasa sara ogiri.

Leyin bi wakati kan ti oga Ade ti ka ese re ro ninu orin, agun bere si ni i bo lara re lakolako, ikunmu n gba imu re jade, oga Ade si n sunkun bi omode lai reni fi egba naa rara.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment