Smiley face

Awon Adigunjale Fo Bank Skye Mole, Gbogbo Owo Inu E Ni Won Ko Lo

Titi di akoko yii, awon agbofinro ile Naijeria ko ti mo ibi ti awon adigunjale ti won pa eniyan merin ni eka banki Skye to wa ni Oja Alaba ni Ilu Eko lose to koja wa ti won si ko opolopo owo salo.

Ojo isegun yii, nibi ti banki yii ti n palemo owo lati gbe lo si olu ile ise won ni awon ole yii ti de ba won lalejo bi eni wi pe babalawo ti difa akoko ti won yoo gbe owo naa lo bee ni isele taa wi yii se se kon-onge ara won.

Eniyan merin lo ku iku ibon lowo awon alokolohunkigbe yii, eleyii ti olopa ati osise banki naa wa lara won.

Obitibiti owo ni won gbe lo eleyii ti enikeni ko le so iye owo naa titi di asiko yii.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment