Smiley face

Tani Yoo Gba Ami Eye BBC Agbaboolu Ile Adulawo To Pegede Ju Lo Fun Odun 2013?

Ile ise iroyin agbaye ti kede awon agbaboolu marun-un to seese ki okan ninu won gba ami eye BBC Agbaboolu Ile Adulawo To Pegede Ju Lo Fun Odun 2013.

Awon wonyii naa ni: Victor Moses ati John Obi Mikel lati Naijeria, Jonathan Pitroipa lati Burkina Faso, Pierre Emerick Aubameyang lati ilu Gabon, Yaya Toure naa ko gbeyin lati ilu Ivory Coast.

Ojo keji osu kejila odun yii ni won yoo kede eni to jawe olubori nibi ti awon oniroyin ti ko din ni merinlelogoji lati ile adulawo yoo ti maa fi orikori leyin idibo tani-oba-ori-odan-ile-Afirika.

»»»
Ko ma da bi eni wi pe mi o so fun yin. Olayemi Oniroyin naa wa lara awon oniroyin ti won yoo peju yan eni ti yoo jawe olubori ninu awon agbaboolu naa. Erkk
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment