Leyin igba ti Aare Goodluck se ipade po pelu awon olori egbe ASUU awon eniyan gba wi pe asiko ti to ti idasesile ASUU yoo rodo lo mu mi.
Sugbon oro tun ti fe yi sori bayii leyin ipada awon elekajeka egbe ASUU ti won pada lana.
Awon kan gba wi pe ki awon figi gun idasesile latari ileri ti Aare se fun won ati ijamba ti idasesile n se fun awon akekoo ti won joko sile.
Awon eka mii ni lailai ala ti ko ni i se ni. Won ni ileri oloselu ko se e gbarale. Ati wi pe enu dundun lasan ni Goodluck fi soro ko si si aridaju wi pe yoo mu ileri re se.
Awon eka ti won tako dida iyanselodi duro tun so wi pe bi awon ba fi le da iyanselodi duro lairi ohun to giriki gbamu, a je wi pe gbogbo ilakaka ati wahala awon ja sasan nu-un.
Lara awon Ifafiti ti won tako aba yii ni University of Ibadan, UI; University of
Benin, UNIBEN; University of Calabar, UNICAL; University of Jos, UNIJOS ati Lagos State University, LASU.
Lara awon awon eka ti won pe fun ki iyanselodi ko duro ni Unilag, awijare won si ni wi pe ohun eniyan n se niyi naa ni i se lasete. Won ni ko ba dara ki awon da iyanselodi duro ki Egbe ASUU maa lo di eniyan yepere loju awon ara ilu ti won n se atileyin fun egbe naa.
Olayemi Oniroyin, ipade taa wi yii ni agbara lana. Olorun nikan lo le petu si won ninu. Pelu bi awon eebo kobitikobiti se n bo lule logido lenu awon eka ti won ni ki iyanselodi ko tesiwaju. Eebo fifo ko rorun, ki eniyan tun maa wa fi agidi pelu ibinu fo eebo lakolako, se mo wi pe iru eebo ko le 'easy' lailai.
Home / Uncategories / Egbe ASUU Ti Pin Si Meji: Boya Ni Iyanselodi Le Wa Sopin Lose Yii Gege Bi Won Se Kowe Re
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
Ki oniroyin yee so ohun ti oju re ko to. Egbe ASUU ko pin si meji rara. Gboingboin ni egbe wa duro. Tee ba farabale, e o ri ibi ti ASUU n lo laipe.
ReplyDeleteIya nje gbogbo yii. Igba ti eko pin si meji, ki wa ni radarada ti e n baka. Ti en fi asiko awon omo ile iwe sofo. Sebi awon kan ninu yin naa ni won lo n gba abetele lowo oloselu alatako ki won lo soju ijoba to wa lode bole.
ReplyDelete@Ogbeni Ogunbote Gbenga, Mo ti gboooo lol
ReplyDelete