Smiley face

Awon Omo Ajah Ti Pa Omo Ilaje Ni Ipinle Eko


O ti pe ti ikunsinu ti n waye laaarin awon omo Ajah ati ilaje ti won wa ni ipinle Eko. Gbogbo igba si ni awon omo Ajah ti won pe ara won ni omo onile maa n dun kukulaja mo awon omo Ilaje eleyii ti won gba wi pe ajoji lasan ni won.

Eleyii lo si faa ti awon osise alaabo fi maa n duro lorita Ilaje lati bu omi tutu si rogbodiyan to ba fe sele.

Sugbon ni ale ojo Aje to koja yii ni okan lara awon omo Ilaje ti oruko re n je Oreofe Olorunlana se agbako iku ojiji, eleyii ti awon kan fi obe gun sakasaka ni ikorita Ilaje.

Awon omo Ilaje fesun kan awon omo Ajah wi pe awon ni won se ise buruku naa. Nitori wi pe ikorita kan naa yii ni awon omo Ajah ti maa duro gba owo lowo awon onimoto ti won ba fe koja si agbegbe naa.

Awon olopa olotelemuye ti fon sita lati mu awon janduku ti won se ise ibi naa. Bi won tile ri won mu, Ogbeni Oreofe to sun sinu agbara eje ko daju wi pe o le pada dide mo.

'Won ti pagun, o ti daju wi pe won ko ni i kadun. Eni to pa akalamagbo ko ma ba won se adehun osu tori wi pe ko ni kosu dandan ni. Eni pa leleke alaso funfun ko ni raso bora lojo to ba wole sun' Awon Odo Ilaje

Awon odo Ilaje n binu. Ikanra ni won si fi n sepe. Bi eniyan ba ri oku Ogbeni Oreofe, anu ikunle abiamo le mu eniyan bu sekun peregede lai mo eye to su.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment