Dokita Arthur Mikaelian lati ilu Russia la gbo wi pe o ti rogbon da nipa sise ogun ti n wo aisan jejere(cancer) eleyii to pe oruko ogun naa ni 'Escozine'.
Orisii eroja kan pataki ti Dokita Arthur fi se 'Escozine' yii naa ni oro akeeke (scorpion venom) eleyii ti iwadii si fi yeni wi pe o nje bi idan to si n gba awon eniyan lowo iku aisan jejere.
Sugbon iyalenu lo je bi awon onimo isegun ilu Amerika se koyin si ise owo Dokita Arthur.
Won ni 'Escozine' ko layole, awon ko si gbara le gege bi ojulowo ogun to daju lati wo aisan jejere.
Ominu n ko opolopo awon onimo isegun kaakiri agbaye nipa bi awon egbe onimo isegun ilu Amerika se koyin si iroyin ayo yii. Onikaluku won si n ro wi pe ko maa lo je eta inu ati rikisi ni won fe tibo aseyesori Dokita Arthur.
Ko ba je ilu Russia ni iwosan ti wa bo si se Amerika naa ni, sebi ka roso modi ka rodi maso kidi sa a ma ti gbofo lo se koko.
Awon onimo kan tun fi kun un wi pe ti ilu Amerika ba tile fe gbogun ti Escozine ko ye ko je kiakia bayii. Nigba ti babalawo se ogun aiku fun omode, ti omode ni ko sise. Se omo naa ti ku na ni lo fi mo wi pe ko sise?
Ju gbogbo re lo, aseyori ni eleyii je ni eka imo isegun. Bi Escozine ko tile se e gbe okan le, apeere n foju han wi pe ona abayo lati se ogun to le wo aisan jejere to see gbokan le ko jina mo rara.
Ibikibi to wu ki e le wa, Olayemi Oniroyin n ki yin.
E ku asiko yii.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
Gbayi!
ReplyDelete