Gege bi Olanrewaju Adepoju se gbe kale ninu ewi re kan to pe ni 'Ironu Akewi'. Akewi se apeere iru ibanuje eni omo ku fun wi pe ko yato si akewi ti won ji ni ewi gbe sa lo.
O ni lati je wi pe oro yii gan-an lo dun Don Jazzy to bee gee to fi pe Wande Coal ni ole a-ji-ise-opolo gbe ni kete ti Wande gbe orin re tuntun jade to pe ni 'Baby Face'.
Don Baba so wi pe orin oun ni, a ti wi pe owo oun ni Wande Coal ti ji orin naa gbe ko to wa so di ti e.
Isele naa dun Wande nipa ona ti Don gba mu oro naa. Wande ni o se je ori ero Twitter ni Don Jazzy ti wa fi aidunnu re han si oun.
"Ero foonu mi mbe lowo re, ki lode ti o le pe mi lori ago to fi je wi pe ori twitter lowa? Nnkan bi odun mewaa ni mo fi sin o ti mo si n se olooto si o, kilode ti itesiwaju mi n run o ninu? Iwo ko ni Olorun o" Wande Coal
"Bi mo tile je eniyan tutu, se iyen wa ni wi pe ke e ma temi loju mole?
Ki n maa laagun ki awon kan maa jere ise owo mi ki won si maa gba ogo ilakaka mi. Awon ole a ji ise opolo gbe!" Don Jazzy
O ti pe ti olorin meji ti n sota ara won. Ona ti jin ti oga ati omose ti n buta si ara awon loju. Sugbon ohun to ba ni lokan je ni ki ololufe meji ti aye n fe sadeede koyin si ara won lori ohun ti ko to n kan rara.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
olayemi iwo lo mo pe ko to ikan....fi iyawo se apejuwe, ki eyan ko so fun e pe oyun ti iyawo ni oun loun ni... ki lo ma se....ibanuje lo je ti elomi ba n ji isu onisu wo.
ReplyDeleteMMmmmmmmmmmmh! Orin Fela lo wa si mi lokan. 'Oro pesi je o, oro di un'
ReplyDeleteO se Omotanwa fun iriwisi re. Thanks