Bi Boko Haram ko tile ti pa awon eniyan tan ni Ipinle Borno, ohun to daju ni wi pe ti won ba n ba lo bayii, ko si igba ti won ko ni run gbogbo ilu naa tan raurau.
Awon eniyan bi merindinlogota ni awon eniyan onise dudu yii tun pa ni Ojobo to koja yii.
Abule kan ti n je Gulumba ni agbegbe ijoba ibile Bama ni awon onise ibi yii ti sadeede yi abule naa ka, ti won si bere si i yin ibon lu omode ati agbalagba, won pa alaboyun ti mbe ninu ilu, won pa okunrin laigbagbe awon obirin, won pa ewure ile, bakan naa ni won pa aguntan oja.
Igba ti won se eleyii tan ni won ba tun dana sun dukia won.
Olayemi Oniroyin, se e wa ri wi pe ti mo ba ni gbogbo Maiduguri ti run se e ri wi pe mi o so asodun oro lasan? Bi eniyan ba je olokan lile, to ba de abule ti isele yii ti sele yoo sunkun kikoro.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment