Smiley face

Irawo Keshi Yipada Dosupa Nla

Leyin ti Ile Naijeria fi eyin Ethiopia janle ni ilu Calabar pelu ami ayo meji si odo ti apapo ayo ti won gba si je merin si ookan.

Ilu Naijeria je ile alawo dudu ti yoo koko pegede lati kopa ninu boolu agbaye ti yoo waye ni ilu Brazil.

Opolopo awon ojogbon elere boolu agbaye ni won si ti n gboriyin fun olukoni elere boolu ti ile Naijeria fun ise takuntakun to se lati jajabo ninu hilahilo taa-ni-yoo-kopa ninu boolu agbaye lati ile adulawo.

Bi o tile je wi pe awon owo ajemonu kan tile wa ti won je okunrin yii eleyii ko da omi tutu si lokan lati gbe ogo ati iyi Naijeria laruge.

"Bi ologbon kan ba ni ohun gbon tan, eni ko simi ariwo ni pipa. Bi o tile je wi pe mi o loju orun lati ri ayo ojo oni, mo dupe lowo Olorun to fi wahala mi pon mi le. Mo si dupe lowo awon omo mi ti won ko doju ti mi. Mo tun dupe lowo awon omo Naijeria pata. Opolopo ise si wa fun mi lati se, mo si gba wi pe Olorun yoo ran mi lowo" Keshi
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment