Smiley face

Leyin Aadota Odun, Obama Ati Clinton Setan Lati Seranti Akoni Ti Won Seku Pa Ni Ilu Amerika

Awon agba loni ti a ba ranti eni mbe laye, o se pataki ka se iranti awon akoni ti mbe lajule orun.

Leyin aadota odun ti awon amokunseka ti seku pa olori ile Amerika nigba kan ri, John F. Kennedy, Aare Obama ati Bill Clinton setan lati bu ola fun okunrin naa ni oju oori re to wa ni Arlington National
Cemetery l'Ojoru ti n bo yii.

Yato si eleyii, Aare Obama tun setan lati fi ami-eye Presidential Medal of Freedom da Bill Cliton lola. Iru orisii ami-eye yii ni JFK filole, eleyii to ku leyin ose kan to fi ami-eye naa da awon eniyan lola fun igba akoko.

Lara awon eniyan ti yoo tun gba orisii ami eye to gaju ni ile Amerika yii ni sorosoro agbaye, obirin bi okunrin, 'erujeje amohunmaworan', Oprah Winfrey.

Ifi-ami-eye-dani-lola yii yoo waye lale Ojoru yii kan naa ni gbongan nla ti Smithsonian Museum of American History nibi yii naa ni Aare Obama yoo ti maa ka apileko re eleyii ti gbogbo eniyan ti n reti.

Sebi eran ara lasan ni awon asebi pa lojosi, awon ologbon aye so wi pe emi Kennedy si wa sibe titi ayeraye.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment