Leyin ti ijoba apapo ti leri wi pe oluko ile eko giga to je ti ijoba apapo ti ko ba pada si enu ise re l'Ojoru ti n bo yii yoo padanu ise re ni awon egbe ASUU ti ka si oro aja ti n gbo lasan.
Alaga egbe ASUU eka ti Ifafiti Ijoba Apapo to wa ni ilu Ibadan, Omowe Segun Ajiboye ti ro awon obi lati maa fi emi awon omo won we ewu nipa titaari awon omo won si ile iwe nigba ti iyanselodi n lo lowo.
"Ijoba ti fa were loyan, o si di dandan ki were bu won je. Emi sebi ijoba awa-ara-wa ni ijoba to wa lode ni. Emi o mo wi pe ijoba alagidi ni. Iyanselodi si n tesiwaju, a ko si ni pada si enu ise a fi ti won ba da wa lohun." Alaga ASUU U.I
Aare egbe ASUU lapapo, Omowe Nassir Fagge naa ti ro gbogbo awon oluko lati maa kobi ara si oro Goodluck. Gege bi oro re, oni bata re ti n dun lakolako ni, o setan ti o ya peregede bi owo aso.
Minisita fun eto Eko, Ogbeni Nyesom Wike se alaye ninu oro re to so lOjobo to koja yii wi pe bi irungbon alagbaro ti wu le ko gun to, eni gbe ise fun un ni oga re.
"Omo ASUU to ba ko lati pada si enu ise gege bi oro Aare Goodluck Jonathan yoo je iyan re ni isu. Bi ikun lo loko ni, bi pakute ni, ni o soju gbogbo wa" Minisita
Gege bi oro awon agba, won ni enikan kii jiyan bi ose ho bi ko ho lodo. E je ki gbogbo wa ka teti loko maa wo ibi oro yoo pari si.
A mo kini kan ni mo n ro lokan, afaimo ko maa lo je wi pe fiimu to gun loro to wa nile yii, boya ni enikeni maa le woo tan.
E ku ikale!
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment