Okan mi baje nigba ti oluko salaye fun wa bi awon oyinbo ajale se pa awon omo ile iwe alakobere ni ilu naa latari wi pe won fi ehonu han bi ijoba ajele se fi owo kun owo ile iwe won eleyii to je ara ona lati fi ara ni awon eniyan dudu.
Soweto ni isele buruku naa ti sele nibi ti Oyinbo funfun ti fi ibon pa awon omo keekeke ti won ko din ni metadinlogbon(27).
Okan mi baje lati gbo iru itan yii. Iwuri losi je fun mi lati gbo itan akoni kan to dide lati koya fun orile ede re.
Baba mi Akanji so fun mi nigba kan ri wi pe kii se gbogbo eni joko si soosi bi Wooli tabi Alfa ni mosalasi nikan ni won n sise Oluwa. O ni gbogbo eni ba jise ti Edua oke ran lati orun ni ojise Eledumare.
Mo feran Nelson Mandela bi eni wi pe ko maa ku mo lailai.
Lara ohun ijoloju ti mo ka ninu itan re ni bi o se maa n gba ejo ro fun ara re ni kootu ijoba awon ajele nigba ti awon ajale pe e lejo.
Nigba ti mo wa ni kekere, ero mi ni wi pe lojo kan maa ni ore ofe lati beere awon ibeere ti mo ni lokan lowo Madiba. Sugbon anfaani naa o yo, akoni lo ko duro dahun ibeere mi.
Lara ohun ti mo fe bi i ni wi pe ni awon igba to fi wa lewon fun odindi odun metadinlogbon, nje awon igba kan wa to kabamo fun awon igbese re?
Ko ba wu mi lati beere iwuri re lati doju ija ko ijoba ajale laini owo ati agbara, laisi ireti boya yoo ye tabi ku loju ija?
Ni ojo keji ti won sin Mandela, ilu South Africa tun pada gbe Mandela soke ni Pretoria to je ibujoko ijoba ilu naa.
Ere ti won fi fadaka se yii ga ni iwon ogbon ese bata eleyii to n se ami isokan. Ere yii kan naa ni won se ni iranti eni iyi ati eye ile Adulawo, Akoni Nelson Mandela.
Oku olowo ni won se fun odun meta.
Oku olosi ni o pe wakata meji.
Oku olomo daseesetan.
Mandela, gbogbo omo ile adulawo n se iranti re. O digba!
0 comments:
Post a Comment