Ni Ojo Kerinla Osu kejila odun ta a wa yii, Gomina Rotimi Amaechi ti Ipinle Rivers soro nibi ipade kan to waye ni ilu Eko eleyii ti won se lati fi bu ola fun Oloogbe Nelson Mandela ti Ilu South Africa.
'Nigba ti e ri ole to jale ti e ko se nnkankan, igba wo ni ko ni tesiwaju ati maa jale re lo pelu irorun? Kini awon ohun igbese ti e ti gbe lati fi opin si iwa jegudujera? O ti di igba melo ti e le won loko pa danu? O di igba ti e ba bere si ni lewa ni okuta pa ka to dekun a ti maa jayin lole' Gomina Rotimi Amaechi ti Ipinle Rivers
'Won jo won yo wi pe won ti yo owo iranwo epo robi, owo iranwo epo to je wi pe N2.3trillion ni won fi ji ko. Kini ohun ti eyin ara ilu se si?
'Kaka ki eyin ara ilu ja fun ogun yin ti won ji ko lo, n se letun pariwo ki woon tun fi kun owo iranwo epo. Owo iranwo epo eleyii ti anfaani re ko de odo mekunnu ti ebi n pa nigboro.
'E tun gbo wi pe N50billion poora bi iso broda Jelijeli, didake le dake bi omi inu amu. Awon isele to je wi pe to ba sele ni awon ilu okeere, ikoko ko ni gba omi, ko gba eyin ko tun gba soso fun ijoba. Gbogbo ara ilu ni won yoo tu jade sita ayafi ti won ba da owo naa pada. E maa je n tan yin owo bi N8trillion ti won ponla bi tomutomu le se atunse nla si ile wa ti won ko ba ko mi bi kolokolo.
'Gbogbo yin le ka leta Obasanjo, e si so wi pe o se le ko iru leta bee. E sebi boya o n gbe leyin awon ara Guusi ile Naijeria ni. Igba ti Obasanjo gan-an wa loye itu ki lo pa? Onikaluku ni lati dide, ki e si ja fun eto yin. Ti olori yin ba kowo yin je ti e ko ba soro, e lomii yoo tun bo sori oye ti yoo tun maa ba 'ise Oluwa' lo bi ti awon olori isaaju.
'Lonii, gbogbo yin kedun iku Mandela, eni to ku leni odun marundinlogorun. Boya leyin mo wi pe inu Madiba ko dun si awon olori Naijeria bi won se so awon eniyan won si oko eru osan gangan saaju ko to wole sun.' Gomina Rotimi Amaechi.
Olayemi Oniroyin, ibi ti mo n lo gan-an mi o ti de be, ibi ti mo n ya lo po lapoju. Ninu iwe Iroyin Punch aaro oni yii ni mo ti ri iroyin kayeefi kan, ni mo fi ni ki n foju yin to. Iwe iroyin se alaye wi pe lara eto isuna ijoba apapo fun odun 2014 ni lati na owo to to bi milionu merinla aabo (14.5M) lori eranko meji ti won wa ni ogba eranko to wa ninu Aso Rock Villa.
Eleyii to tun mo si wi pe okookan awon erankan meji naa yoo maa na to egberun lona ogorun mefa owo naira (N604,167) losu kan pere.
Aimoye awon eniyan lo je wi pe won tiraka lati ri egberun mewaa jeun laaarin osu kan, awon mii ko tile ri to egberun mewaa gege bi owo osu ti won n gba, nigba ti awon kan ko ri nnkankan rara jeun.
E maa je n tan yin, ibanuje nla ni iru iroyin bayii je fun awon ti won ko ni agbekele ohun ti won yoo mu lo si ona enu depodepo wi pe won yoo ra aso odun ti won yoo wo sorun. Aimoye odo ni won jade ile iwe ti won ko rise se. Awon ti won ri ise, ise ti won ri ko to won jeun won kan fi n maneeji ara won. Awon dokita da ise sile, o ni iye osu ti awon ASUU se nile ki won too da won lohun. Sibesibe, awon ijoba si roju raaye omo eranko nigba ti ebi n pa omo eniyan. Bi ijoba Naijeria ko tile so wi pe eranko wule ju awon eniyan lo, ise ati iwa won ti ja ka mo ero okan won.
Ni Ilu South Africa, itan so fun wa wi pe awon oyinbo alawo funfun ni won so awon eniyan dudu deru. Sugbon ni ilu Naijeria, awon eniyan dudu (awon eniyan ti a yan si po, awon asaaju ti a fi enu ire ki) ni won ba wa lokan je ti won si fi irin gbigbon jo wa nidi.
Walahi, ejo n mbe lorun. haaba!
ReplyDeleteOdun Keji re ti mo ti jade ile iwe ti mo n wa ise ti ko si ise ko si nnkankan. won wa ni ole n po si ni ilu. bawo ni ole ko se ni po. nigba ti awon kan ko aduro owo bayii ti won si n na ni inakuna. ogbon a ti kowo je nii gbogbo ogbon ti won n da, aye won de maa baje ni
ReplyDelete