Smiley face

Kilode Ti Won Fi Bi Jesu Si Ibuje Eran?

Lati nnkan bi ojo meta seyin ni okan mi ti n ro nipa ibi Jesu (bi a se bi Jesu) ati bi akosile se safihan re gege bi olugbala araye. Ohun kan ti mo si n ro naa ni wi pe o se je ibuje eran ni won bi iru eniyan bi Jesu si?

Ni gbogbo igba ti mo ba wa ni ile eko isinmi lojo Aiku, oluko ojo-isinmi wa maa n so fun wa wi pe bi Jesu tile wa ni aworan ara eniyan, omo Olorun ni i se. Omo Alade ni lode orun ko to di wi pe o pinnu lati gbe awo eniyan wo lati wa ku fun ese araye.

To ba je wi pe lotito ni wi pe omo alade orun ni i se, kilode ti ibuje eran (ibi idoti ti ko ba oju mu) fi jeyo ninu itan igbesi aye re?

Yato si eleyii, aimoye awon omode ni Oba Herodu seku pa nigba to n lakaka lati pa Jesu latari ayoka to rika ninu iwe asotele eleyii to so nipa oba tuntun, Jesu Olugba araye to n bo. Aimoye abiamo lo sun ekun kikoro nigba ti oba Herodu seku pa awon omo won. To ba je wi pe Jesu wa gba aye la lotito, iku se pa aimoye omo wewe nitori iwasaye olugbala?

Nikete ti Jesu ti wa saye ni awon obi re ti kosi hilahilo ti won n gbe e sa kiri tori awon ika eniyan ti won fe seku pa a. Sugbon ero temi ni wi pe to ba je wi pe omo alade orun looto ni Jesu ko ye ko ni isoro kankan lode aye?


Bi eniyan ba tejumo awon akosile orisiirisii lai ronu jinle, otito oro le bo so nu. Akiyesi mi pada salaye ogbon fun mi. Alayemi ko ti tan, e maa ba mi bo..

Ibi eniyan (bi a se bi eda eniyan) ko ni i se pelu iru eniyan ti eda je lati ode orun tabi ohun ti iru eniyan bee yoo gbe aye se. Isoro tabi ohun ti eda n la koja lopo igba ki i se afihan iru eni ti eda je gan-an ni pato.

Bi o tile je wi pe Jesu koju awon isoro yii nigba kekere ati apejuwe ibi ti won bi si gege bi alaini, sugbon o so wi pe gbogbo agbara laye ati lorun owo oun lowa. Bi gbogbo agbara ba wa lowo Jesu eyi tunmo si wi pe gbogbo ola, ire ati aseyori wa lowo re pelu.


Awon eniyan bi egberun marun-un lai ka awon obirin ati omode lo fun lounje lojo kan soso, o ji oku dide, o fun alailoju ni oju tuntun, o fun aro ni ese tuntun. O ni enikeni ti o ba gba oun gbo, o ni ki i yoo ku sugbon ni o ni iye, eyi ni wi pe a gba a la lowo iku ayeraye. Jesu ku a tun pada ji dide. O ni bi won ba fe won le wo tempili, oni ojo meta pere ni oun yoo fi ko pada. { E kiye si awon gbolohun yen.... eleyii koja oye eniyan}


Eyi gan-an ni eri ati ireti agbara irapada; Jesu ku o tun jide pada. Iyanu !

Bi eniyan ba ka ibere aye Jesu lai ka igbe aye re to gbe yoo soro lati le gba wi pe olugbala ni looto. Ibere re tabi isoro ti o n la koja ko ni itunmo si iru igbe aye ti o pada gbe. Ohun gbogbo to n sele si o fun igbega re ni, bi awon Parisi ati Sadusi se n gbiyanju lati te ogo Jesu ri, bee ni okiki re tun kan si.

Ti o ba ti n sukun, mo ro o ki o nu oju re nu. Bi awon isoro to n la koja se po bee naa ni igbega re yoo se gbooro to. Olorun ko da o lati maa gbe ninu aisan tabi aini, ijakule tabi ibanuje. Ero Olorun fun iran eniyan, ero rere ni. Ti ko ba ri bee kilode ti Jesu fi wa saye?

Olorun fe araye to bee gee..., ife re si wa lo mu fi omo re se irubo lati we ese aye danu ki awa maa ba a di eni itanu niwaju Oba mimo.

Lara awon idi ti Jesu tun fi wa ni lati wa so wa di alaseyori. Oro Olorun so wi pe fun idi eyi ni omo Olorun se fi ara han lati wa pa ise esu run (airina, ibanuje, aisan, ijakule abbl).

Odun 2014 kan ilekun, je ki ireti re ko ga. Maa beru, si maa foya. Iwo gbagbe gbogbo ohun to ti sele seyin. Sebi odun 2013 tile dara ju 2012 lo fun o? Iwo wa maa yo nipa ohun otun ti 2014 mu da fun iwo ati idile re. Odun re ni.

Iye awon ti won ba gbe okan won le Oluwa ki i yoo jogun ofo. Oro Olorun so wi pe iye awon ti won ba gbagbo, awon wonyii ni i se omo Olorun. Eniyan ko le je ebi kan naa pelu Olorun to da aye ati orun ko pada gbe aye inira ati ibanuje.

Olayemi Oniwaasu (haa! Olayemi Oniroyin ni mo fe wi.....erkk), mo wa ki gbogbo onigbagbo aye wi pe won ku odun Keresimesi, a si ku ipalemo odun tuntun to n bo lona. Bi e ba pa adiye, e maa gba Olayemi omo oba. Bee ba pa maalu. e seran Oniroyin onigege ara to ki yin ku ewu odun tuntun.

Odun ayo la o se o!
E ku odun!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

5 comments:

  1. Olayemiiii, O wiiii reeeeeeee

    ReplyDelete
  2. E se oo. E ku odun ooo. Mo n reti nnkan odun ooo lol

    ReplyDelete
  3. E se oo. E ku odun ooo. Mo n reti nnkan odun ooo lol

    ReplyDelete
  4. Merry Xmas to u my boss. U get mouth like anything. love u

    ReplyDelete