
Bi omo eniyan se n pa ara won jaye bee naa ni omo eranko n se ninu igbo. Omo erin lakatabu yii lo se agbako iku ojiji nibi to ti n mu omi to rogun sinu koto ni oun nikan. Omo erin ti awon onwoye so wi pe ko ti le ju bi omo odun meta si merin lo ni kiniun ololaaju le sare to si mu eyin re gun bi eshin.
Bi o tile je wi pe erin naa sare bi ko bo lowo iku ojiji ti n le bo leyin, sugbon ere sisa re ko to nnkan rara debi wi pe iku fi le fooda.
Igba ti erin naa de ikorita ibi ti ko ti le lo mo, kiniun naa bere si ni lo mo o lorun titi to fi mu eyin re bale
Sugbon leyinoreyin, erin subu nigba ti ko ni agbara mo lati tesiwaju.
Awon kiniun pada di meta nigba ti eran ti dele. Odun eran jije fun awon kiniun Hwange National Park ti ilu Zimbabwe.
'Bi o tile je wi pe isele naa ba ni lokan je, sugbon ohun to daju ni wi pe oju ko le fe iru e ku ninu igbo. Iran eran ni i pa eran jaye ninu igbo. Iriri yii ti a ri ninu igbo ilu Zimbabwe je ohun ti ko ni kuro lokan wa kiakia' Ogbeni Haa
Olayemi Oniroyin, boya ni won ti bimi lodun ti Ayinla Omowura koko lo si Mecca akoko to lo. Sugbon orin to ko lodun to de lati Saudi lo le tente si mi lokan nigba ti mo n se ayewo iwadii Kurt ati Haa ti won fi aarin ilu sile lo sinu igbo irumole ni ilu Zimbabwe.
Ti eyin naa ba mo orin naa, e le ba mi ko:
'Mecca alalobo ni ti wa oo 2ce
Ori ti yoo royin ogun ko ni ku
Ayinla re Mecca o bo o
Mecca alalobo ni ti wa'.
mmmmmmmmmmmmmmmmhh! walahi ise gidi le se. Olorun yoo tunbo maa fun yin se.
ReplyDeleteOlayemi, I just like your creativity though Yoruba could be very difficult to read atimes. Kudos to you. you are the best. keep it up.
ReplyDeleteThanks so much. #Appreciate. Stay blessed
ReplyDeleteE ba wa ki Kurt ati Haa won gbiyanju gidi gan-an. a ko ni se agbako iku o. taa ba lo sajo, ayo la o pada wale. iku ojiji ko ni je ti wa o. won ku ise iwadii sinu Igbo irumole.
ReplyDeleteAmin oooo
ReplyDeleteNo kii awon ojogbon bi Kurt ati haa pe won Ku ise takun-takun fun aseyori ise yii
ReplyDeleteO ku ise opolo
ReplyDeleteKi Olorun Maa fi iso re so wa lowo awon ota aleni ma deyin o, Olayemi o! @ iwo, @ emi, @ gbogbo awon ololufe re, a o ni se konge aburu o!
ReplyDeleteKi Olorun Maa fi iso re so wa lowo awon ota aleni ma deyin o, Olayemi o! @ iwo, @ emi, @ gbogbo awon ololufe re, a o ni se konge aburu o!
ReplyDelete@Akinlabi Amin ooooooooooooooo
ReplyDeleteOlayemi, keep moving, the world will talk about you soon. This is amazing. U just took us to Aminal Planet Yoruba lol
ReplyDeleteAburu ko ni ya lodo wa wa ooo. e ku ise Olayemi
ReplyDeleteThank you all. I can't just stop loving u. #AwonEniyanPataki
ReplyDelete