Smiley face

Gbogbo Aye Se Iranti Bisi Komolafe To Ku Lojosi

To ba je wi pe a ki i ku laye ni, bawo ni ko ba se dun to. Ko seni to wa saye ti koni pada lo sorun, Edumare ma je ka fi ojo olojo lo.

Oserebirin Bisi Komolafe koja lo sorun lojo kokanlegbon osu kejila odun 2012 (31/12/12) ni ile iwosan UCH to wa ni ilu Ibadan.

Opolopo awon osere ni won peju si St. Mary's Catholic Church ni Oke Padre, Ibadan lati se isin ikeyin fun Bisi eni ti awon eniyan so wi pe oyun lo ba ku.

Bi eniyan ti wule ko daju bi ose to, to ba tele won de Catholic Church Cemetery ni Oke Are ni ilu Ibadan nibi won ti gbe Bisi wo inu koto ni oun nikan soso, eniyan yoo damiloju poroporo.

Igbe ekun n pe ekun ran nise ni, enikan ko si roju lati ni ki enikeji dake ekun lojo kerin osu kinni odun to koja.

Okan ninu awon ore Bisi eleyii to ko lati fojuhan salaye fun awon oniroyin wi pe otito ni Bisi se oyun ni ile iwosan kan ki won to gbe lo si UCH nigba oro yiwo.

Gbogbo aye ranti Bisi Komolafe lonii, isele naa si ba ni lokan je gidi. Oju lo n kan majesin ti n ku, sebi to ba dagba orun naa ni o pada si.

Omo odun metadinlogbon (27) ni Bisi nigba to ku. Omo ilu Ibadan ni. Ile iwe LASU lo si ti kawe gboye akoko. Bi o tile je wi pe o ni oko, sugbon Bisi o fi omo sile saye lo.

Bisi, gbogbo awon ololufe re n se iranti re. Gbogbo won ni won wi pe iwa re tutu bi adaba. Awon kan ni ewa re ko pe meji lagbo amuludun. Alaye Bolaji Amusan ni wi pe ogbon ori ati ebun re ki I se agbelero rara.

O di gba!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment