Smiley face

Ti E Ba Ni Anfaani Lati Ba Aliko Dangote Soro Kini Ohun Naa Ti Ba Fe Ba so, Nitori Wi Pe Ona Ti Si Bayii Lati Ba Baba Olowo Soro?

Alhaji Aliko Dangote ti gori ero iwiregbe ayelukara ti Twitter lana ode yii pelu oju opo re to pe ni @AlikoDangote.

Alh Aliko Dangote ti ko tile ti i se atejade ohunkohun ki awon alamojuto ero Twitter too gbe ounte le oju opo re, eleyii to se apejuwe wi pe ojulowo Aliko Dangote looto lo ni oju opo naa.

Sugbon leyin igba die ti Olayemi Oniroyin tun pada ye oju opo naa wo, a ri wi pe Dagote ti te oro ikinni odun jade si awon ololufe re, bakan naa lo fi idunnu re han pelu bo se darapo mo Twitter.

"@AlikoDangote: Glad to be on Twitter. Wishing you all a prosperous New Year. Stay positively committed to achieving your dreams, nothing is impossible."

Awon alagbara aye bi meje ni Dangote n tele loju opo re, lara won ni Bill Gate nigba ti ogunlogo awon eniyan si n wo tele Aliko leyin bi igba awon oromadie n wo tele adiye agbebo leyin.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment