Smiley face

Kini Gomina Abiola Ajimobi Se Nipa Oba Alaye Ti Won Fun Lewon Gbere Latari Esun Ipaniyan?

Gomina Abiola Ajimobi ti siju aanu wo Oba Gabriel Adepoju Adeyemo ti Oko-Ile to wa ni Ogbomoso ti won da ewon gbere fun ni odun 2011 latari esun ipaniyan.

Lara awon ti won da ewon gbere fun ti Gomina si sile lati lo sodun ni ile won ni Isaac Ogunniyi, Gabriel Ojetayo ati Lukman Ajibola.

Yato si awon ti won da ewon gbere fun, awon elewon bi mejila(12) miiran ti won di ero ewon loke Agodi ni ilu Ibadan latari oniruuru esun naa ni won tun gba idalare lati owo Gomina Isiaka Ajimobi.

Agbejoro fun ijoba to tun je komisanna fun eto idajo, Arakunrin Ojo Adebayo lo kede eleyii. Gege bi oro re, oni Gomina se eleyii lati fi se ajoyo odun tuntun 2014.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment