
Awon Yoruba bo, won ni ojo iku erin, orisiirisii obe laari. Ojo won ba n sodun ajobo lero n po pitimo.
Ni bayii ara orin setan to fe san, iji orin setan to fe ja bi Sango Olukoso oko Oya.
Nibi ayeye Ami Eye Grammy agbaye ti yoo waye lojo Kerindinlogbon Osun Kinni Odun 2014 (January 26, 2014), won ti kede toko taya Jay Z ati Beyoncé gege bi onkorin pataki ti won yoo fi orin aro to gbamuse da awon eniyan laraya.
Ajumokorin Jay Z ati Beyoncé ti di iroyin agbaye eleyii ti opolopo ko le duro lati ri ojo ariya alailopin to n bo lona naa.
LL Cool J ni yoo dari ayeye lojona, Olayemi Oniroyin ni o si royin faraye gbo. E gba mi gbo, oke ni aga mi wa lojo naa. Errk
0 comments:
Post a Comment