Awon agba ni oju ni i kan mojesin ti n sare lo sorun, sebi to ba dagba orun naa ni o pada si. Bo se je wi pe oro naa ba ni lokan je gidigidi, aimoye aditu lo tun jeyo ninu isele to n se gbogbo eniyan ni kayeefi.
Omo ile iwe gbogbonse ti a mo si Poli ti ilu Ibadan ni Timilehin Ayobami Ogundare je.
Ni ojo kerin osu taa wa yii (January 4), Ayobami gbiyanju lati ko sinu odo Ogun sugbon awon figilante ti won mbe nitosi ko lati gba ki omo yii ko sinu omi.
Awon figilante bere idi ti omo naa fi fe seku pa ara re eleyii ti ko jewo fun enikeni. Okan ninu awon figilante naa beere foonu alagbeka re eleyii to so wi pe oun ko ni dani sugbon siimu foonu oun wa lowo oun. (Ayobami moomo yo siimu re kuro ninu foonu re ki awon eniyan re le ma mo bo se rin).
Ko pe die leyin ti won wa foonu ki siimu yii bo ni awon eniyan re bere sini pe wole. Awon figilante salaye ohun to sele won si kesi won lati wa mu omo naa lo si ile.
Sugbon iyalenu loje wi pe Ayobami pada pokunso sinu yara re nigba ti won dele won to wa ni agbegbe Ilupeju, Baasala, Asero ni ilu
Abeokuta ni ojo Karun-un osu kini odun yii (January 5, 2014).
Okan ninu awon ebi omo yii tile jewo fun awon oniroyin wi pe ati odun to koja lo ni Ayobami ti n gbiyanju ati seku pa ara re eleyii ti ko ni anfaani lati sebe saaju ko to wa pada pokunso pa ara re sinu ile.
Ohun ti a tun gbo ni wi pe ati ibere odun yii ni won ti n wa omo naa to ko ti ko yoju sile. Awon kan si so wi pe ilu Eko ni omo naa gba lo. Ojo Satide to pada wo ilu Abeokuta pelu oko oju irin reluwe eleyii to so ni Lafenwa. Ati Lafenwa ni Ayobami ti mori le Ajitaadun titi lo si Arakanga nibi to ti fe lo kan lu odo lai mowe.
Iwadii si n lo lowo nipa ohun ti Ayobami lo se ni ilu Eko boya o niise pelu bo se gba emi ara re. Ati wi pe awon eniyan wo lo lo ba nibe?
Ninu yara Ayobami ko to di wi pe o gba emi ara re, omokunrin naa ko leta sile lati toro aforijin nipa bo se gba emi ara re. Bi o tile je wi pe ko so idi to fi wu iru iwa bee.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
Ha eleyi toju sumi o,abi bawo ni eeyan sele ronu lati pa ara re,iru kini baa sele ti o wa jepe ki eniyan pa arare lo to,afi ki olorun ro awon ebi re loju o
ReplyDeleteIbanu nla. Sugbon awon Yoruba ni ti ko ba nidi, obirin kii je Kumolu.
ReplyDeleteEmi o ro wi pe oju lasan ni iru oro bayii. Awon obi omo naa si jebi lopolopo. Igba akoko ti won ti fura wi pe omo yii ti n gbiyanju ati pa ara re lo ye kan ti mojuto. Sebi won ni agba kii wa loja ki ori omo tuntun wo? Nigba awon agba wa nile ti agbara tun ya wole gbe omo tuntun lo, e ri wi pe nnkan yan?
ReplyDelete