
Ko si iru oro itunnu ti eniyan fe so fun eni ekun pa iya re je. Sugbon ju gbogbo re lo, ipokipo ti eniyan ba wa laye ko maa dupe fun Oba olorun Oba ni.
Omobirin Ajifa Khatun lati ilu India ni ko dagba soke mo lati igba to ti ku die ki omo naa pe eni odun meji. Omo naa ti to eni odun mokandinlogun (19) bayii sibesibe ipo omo odun meji si ni ago-ara re wa.
Awon aburo Ajifa: Danish (8yrs), Rabiya (14yrs) ati Rini (17yrs,).
Odun 1994 ni won bi Ajifa to je egbon gbogbo won eleyii ti awon omo iya n toju bi eni wi pe oun ni aburo patapata.
Nigba ti awon aburo re ti bere ile iwe ti won si ti n se awon ise ile, Ajifa to je egbon won ko tile le pe ju 'Baba' ati 'Maa' lo. Bi o ti le je wi pe awon onimo isegun fi obi omo naa lokan bale ni awon igba kan wi pe oseese ki omo naa tun bere si ni dagba sugbon akiyesi ise iwadii tun salaye wi pe oseese ki omo naa wa titi bee lailai.
![]() |
Ajifa n sere pelu awon omo wewe adugbo |
Ajifa je enikan to maa n rerin ni gbogbo igba, o si maa n feran ati sere pelu awon omo wewe adugbo. Akiyesi baba re ni wi pe oseese ki Ajifa mo nipa ipo to wa sugbon ko ma le soro jade lati beere nipa iru aisan ti n se oun.
0 comments:
Post a Comment