Ohun ti ko daa ko loruko meji ko daa naa ni i je. Awon ore meji lo fi ija peeta ni agbegbe Tafawa Balewa Square to wa ni ilu Eko latari 'omoge onidodo'.
Ninu ija ajakurakata yii ni Christopher Ugbeni ti fi igo gun ore re, Saheed Hamza eleyii to fi esun wi pe o fe maa ji oun nisu wa je.
Nibayii, awon olopa ti gbe Christopher Ugbeni lo si ile ejo Tinubu magistrate's court ti ilu Eko pelu esun jagidijagan ati ete ati paniyan ti won fi kan an.
Onidajo Y. R. Pinheiro bere lowo Ugbeni boya o gba wi pe lotito ni oun jebi esun naa tabi beeko.
Ugbeni salaye wi pe ohun o jebi isele naa rara. O ni eni to ba gba iyawo eni ota eni ni irufe eni bee. Ati wi pe iru eni bee le seku pani ti eniyan ko ba ni ifura.
Bi o tile je wi pe ile iwosan ni Hamza si wa nibi won ti fi bandeeji we ni gbogbo ara eleyii ti ko fun lanfaani lati yoju si ile ejo.
Nibayii, adajo ti sun igbejo naa siwaju di ojo kerinla osu kinni odun taa wa yii(14/1/13).
0 comments:
Post a Comment