
Senato Magnus Abe ti won ni awon olopa ta nibon nibi ipade egbe APC to waye ni ilu Port Harcourt lojo kejila osu yii ti ranse pade sile lati ilu London to ti n gba itoju lowo.
'Mi o ni ohun pupo lati so ju lati fi okan awon eniyan mi bale lo, awon afenifere ati awon omo Naijeria pata. Ara mi tunbo n ya gaga sii lojoojumo ni, mo si gbagbo wi pe ese mi ni maa fi rin pada wa sile.' Senato Magnus.
Titi di akoko yii, won ko je ki enikeni mo ile iwosan ti won gbe lo nii ilu London. Bi o tile je wi pe Bola Tinubu ati awon kan ninu egbe APC ti lo se abewo si ni ilu Oba to wa.
0 comments:
Post a Comment