Smiley face

Sky Whale: Baalu Tuntun Alagbara Bi Alujannu



 
Oruko ti won n pe baalu naa ni Sky Whale nigba ti awon kan tun dape gege bi 'Whale-Like Plane'. Orisii baalu kan eleyii ti imo ijinle awon oyinbo tun setan lati gbe jade fun lilo iran omoniyan ni Sky Whale yii je.

Lara ohun ara oto ti baalu naa ni ni wi pe, baalu naa ni agbara lati se atunse si ara re to ba baje loju ofurufu ati wi pe ko si ibi ti baalu naa ko le ba si to ba ni lati ba kale ni pajawiri. Yato si wi pe baalu naa ni inu nla lati gba opolopo ero, won ni baalu naa tun le pin yeleyele nigba to ba seese to fe ni ijanba nigba to ba fe ba kale ni ona ati doola emi awon ero to wa ni inu baalu naa.
Kii se wi pe won ti se baalu yii ni gidi, iwadii imo ijinle kan fi daniloju wi pe ohun to seese ni. Sebi owo to ba ti niye ni, abuku kan-an

Oscar Vinals lati ilu Spain ni eni to mu ero yii wa saye.

  



 



Gege bi alaye awon onimo ijinle ati atotonu won nipa baalu aramonda ti won fe bere ise le lori yii, won ni baalu naa ni agbara lati ka apa re ko ati lati bo apa re sile lotooto gedegde.
 
Won ni agbara ti baalu yii ni lati bo apa re mejeeji sile yii wulo nigba ti baalu ba fe ni ijamba nigba to ba fe ba kale. Ti baalu ba bo apa re mejeeji sile ko ni je ko raye kolu ohunkohun to le sokunfa ijamba fun awon ero inu oko baalu to wa ni aarin meji apa baalu naa.

Koko kan to tun jeyo nipa baalu yii ni wi pe oni agbara lati fosoke lojukan to wa lai se wi pe o sare siwaju bi awon baalu nla to ku. Eyi ni wi pe ti baalu naa ba wa sile ni ibasile pajawiri sibi to fun gaga, o tun le gbera soke laisi idiwo kankan. 
 

Gege bi Oscar Vinals se salaye, bi irin-ajo baalu ba se to ni yoo so iye igba ti baalu naa yoo pada wa sile lati ro epo kun epo inu re ko le de ibi ti n lo layo. Sugbon ko ri bee pelu Sky Whale (alujannu inu afefe), o le rin aimoye maili lai duro. Yato si wi pe oni aye ile epo to jinnu daada ju awon baalu to ku lo, oko baalu naa tun n lo solar eleyii to fi n gba agbara kun agbara nigba to ba n fo loju orun bi eye asa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment