Smiley face

Wahala Ti Be Sile Ni Ilu Brazil Nitori Boolu Agbaye Ti N Bo Lona



A se otito ni oro awon agba to wi pe; 'Aja to yo ko le ba eyi ti ko yo sere'. Awon agba naa lo tun wi pe okun inu ni eniyan fi n gbe tita. Eniyan ti inu re ko dun ko le mu inu elomii dun lailai. Wahala ti be sile ba yii ni ilu Brazil, opolopo dukia lo si ti sofo bi omi efo. 


Aimoye awon eniyan bi egberun ni won tu jade ni Sao Paolo lana ode yii lati fi aidunnu won han si ijoba ilu naa nipa bilionu lona bilionu owo dola ti won n na lati fi gba alejo idije ere boolu agbaye ti yoo waye ninu odun yii nigba ti aimoye awon eniyan to wa ni ilu na kori ounje je kanu.

 
Opolopo awon omo naa ilu ni won so wi pe ijoba n fi ara ni ara ilu nipa iwa jegudujera, airi ise se awon odo, eto ilera ilu naa to ti di guguru atepa, eto oro-aje ti di akurete, nigba ti mekunnu si n gbe ninu inira ati ipayinkeke.


'Bi eniyan ko ba tokan kii pe ara re ni meji, ba wo ni ebi yoo se maa pa wa ti awon ijoba yo si maa fon owo danu nitori boolu lasan?  Eni ti won ba bi da ko te pepe ere boolu losu kefa odun yii ti o ba ni jeyan re nisu.' Olufehonuhan
















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments: