Agbegbe meta ọtọọtọ ni awon onise ibi kan ti won fura si gẹgẹ bi Boko Haram ti pitu ọwọ won nigba kan naa lana ni Ipinle Adamawa ti won si pa awon eniyan bi metadinlogoji(37). Isẹlẹ yii lo sele lọjọ keji ti won pa awon omo ile ẹko to wa ni Ipinle Yobe.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
Ee ti je? Ki ni eyin aladura ati ojise Olorun ile Nigeria n wo! Ohun ti ipa eniyan ko ka, e sa mo pe ipa Baba mi orun ka a, to fi mo Boko Haram; abi e ti n pe e! E je ki gbogbo wa gbogun adura ti awon obayije wonyi ki won o ma baa da jinnijinni bo gbogbo wa. Emi ko so pe ki e ya ojo kan sile fun adura. Adura to le ran won ni adura idakonko nigba gbogbo pelu ooto inu. Nje ipa won to ti Golayati? Dafidi nikan lo pa a pelu iranlowo Olorun oba.
ReplyDeleteKoko adura ti Baba yan gbogbo wa nile loke lodo ati leyin odi ni pe:
Ki Olorun gba agbara lowo awon amookunsika ile Nigeria, ati Bobo Boko ni ati awon agbodegba won, ki won o di alailagbara. Baba Orun mo bi oun yoo se se; tiwa ni ki a gba adura. Won ni adura oplolopo yin ni ko ti inu wa. Meloo ninu yin lo se tan lati ra epo si oko re ki won si bere si i gbadura yi ka ala Nigeria. E je ki owo yin kan owo. Bi awon kan ba bere ni Ile Ibo; ki awon kan se tiwon ni Ile Yoruba. ki awon ojulowo aladura Oke-odo Oya naa pade yin. Laise aniani, e o royin ogun. Adie ni i pitan kooli, awa la o reyin onise ibi. Bonkele ni awon eniyan maa n fi iru adura yii se. Emi ko so pe ki e kede re ki e too se e. Awa ti se iru re nile Geesi, adura wa si gba. Ko pe osu mefa ti Olorun fi gba agbara lowo awon ayonilenu.
Nje otito ni pe owo te okan ninu Boko Haram to lo si Soosi TB Joshua? Awa ri i ninu TV ni a ko ti i ri eni lati so fun wa. Bi eyi ba ri bee, ti Agbara Emi Mimo ba le mu Boko Haram so bi eyi ti a ri ninu TV naa, ireti n be fun eyin onigbagbo ile wa, Naijiria. Woli TB Joshua, e ku ise Oluwa. Ose to ko ja ni mo beere pe ki ni e wo. Ko kuku si ohun ti adura ko le se. E ka ohun ti mo ko tele lori oro naa. Emi Mimo gbe Boko Haram lule bi eni n tefon.
ReplyDelete