Smiley face

Won Ti Gbe Patience Jonathan Lo Silu Jamani Fun Itoju


Iroyin kan lo lu jade lati ile ijoba apapo l'Abuja, eleyii to n so nipa ipo ailera iyawo Aare ile yii, Patience Jonathan.

Gege bi a se gbo, iyawo Aare ti dubule aisan lati bi nnkan bi ose melo kan seyin eleyii ti ko fun ni anfaani ati yoju si pupo ninu awon ipade to ye ko ti kopa.


Oro asiri ni won fi bi won se gbe iyawo Aare lo si ilu Germany fun itoju se, awon oniroyin ti won si ba awon osise asoju ile ijoba apapo soro lana so wi pe alaafia ni iyawo Aare wa, ati wi pe iya naa sese je iyan funfun to ni ogede die ninu ati obe egusi to kun fun opolopo eran kundi ati eja osan tan ni.

Sugbon ile ise iroyin Sahara Reporters to tu oro naa jade salaye wi pe ko ye ki ijoba maa gbe iru oro naa pamo fun awon omo Naijeria niwon igba to je wi pe owo Naijeria ni won fi lo toju re.

Ana, ojo Abameta ni baalu nla gbe Patience Jonathan fo soju orun. Adura wa si ni wi pe ki Olorun fun ni alaafia.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment