Ni ana ode yii, awon Ipinle bi merin to
je ti egbe oselu APC ni baalu Aare Goodluck Jonathan fo de fun abewo si
awon oba alaye ilu naa.
Awon ipinle naa ni Oyo, Osun, Eko ati Kano.
Awon
Yoruba loni ise igbonse, a ki i fi ran omo eni ni Aare ile yii fi ise
abewo naa se nibi ti o ti n fa oju awon oba alaye yii mora lati yoju
sibi ipada pataki kan ti yoo waye laipe.
Ipinle
Osun ni Aare ti yoju si Ooni ti Ile Ife, Oba Okunade Sijuwade Olubusi
ii; ni Ipinle Oyo ni won ti salaye fun Aare wi pe Oba Lamidi Olayiwola
ti Ilu Oyo ni ko lo ri; Oba Rilwan Akiolu Olowo Eko naa gba Aare lalajo
lana ode yii pelu Emir ti Ilu Kano, Alhaji Ado Bayero.
0 comments:
Post a Comment