E le ka apa kinni Isẹ Iroyin Ati Isubu Awọn Akọni [NIBI]
Bi o tile je wi pe ise akede wa ninu ise iroyin, sibesibe ise iroyin ki i se ise akede. Iroyin je okun eleyii to so awujo papo gege bi osusu owo tabi igi leyin ogba ti awon awujo fehinti lati da alaafia pada nigba isoro, reti nigba ti awon eniyan n ba okan je, imole nigba ti okunkun sibole, olaju nigba ti oju awon eniyan dudu, oye nigba awon eniyan n siye meji.
Bi o tile je wi pe iwa jegudujera ati ohun ti Ojogbon Akinwumi se alaye rere
gege bi Sawo-Sogberi je ohun kan pataki eleyii to mu ise iroyin padanu pupo
ninu agbara re. Gege bi Akinwumi se so, oni awon Sawo-sogberi ni eniyan kan ti
won maa se bi awo tabi ojulowo ti won ba ri awon ope tabi awon ogberi ti o si
je wi pe won ko mo nnkankan sugbon nikete ti won ba ri awon awo gidi, asiri won yoo
tu won yoo si pada di ogberi.
Gege bi
Oloogbe Bob Marley naa se so, oni bi eniyan ko ba mo ibi ti n lo laye, o didi
dandan fun iru eni bee lati mo ibi to ti n bo.
Nipa wi
pe opolopo oniroyin ti so koko ohun ti
ise iroyin dale nu eleyii lo si mu adiku ba agbara Ise Oniroyin ati bi awon
eniyan awujo se so ireti won naa nu ninu pataki ise iroyin lawujo wa.
Eto eko
ile wa ko wuni lori mo. Bi o tile je wi pe ninu ero awon agbalagba aye igba kan
ni wi pe ogun pataki ti baba le fi sile fun omo ni eko kiko. Subon laye ode
oni, oro ti yato si ti aye atijo. Pupo ninu awon akekoo to ye ko jade ni ile
iwe lati wa yanju isoro awujo lo tun pada di isoro ati eru nla ti awujo ko mo
ibi ti yoo gbe won dasi.
Eto eko wa ku die kaato, mo ti tenu mo. Ko si di igba ti enikeni ba pariwo re ki oro naa to ye wa nitori ohun ti gbogbo wa mo naa ni.
Ekeji ni wi pe awon akekoo ko ran ara won lowo lati lo ko awon eko to ba iru eda eniyan ti won je mu tabi ohun to ni i se pelu ebun tabi ohun kan ti Edua oke da won mo. Pupo awon akekoo fe ko eko nitori owo tabi okiki ati iyi to ro mo eni ba le ko iru eko bee pari. Igba ti opolopo won wa jade ile iwe ni ogbon ori won wa pada di omugo latari airise se.

0 comments:
Post a Comment