Smiley face

Won Ti Pa Omo Naijeria Si Ilu Malaysia


Gege bi adura omo Oodua, won a ni ohun ta a je la n wa, Edua oke maa je a pade ohun ti o je wa. Omo Naijeria kan ti oruko re n je Adelabu Tunde lati Ipinle Ekiti la gbo wi pe awon olopa ilu Malaysia kan ti gbe ibon fun lagbari lainidi kan pataki.

Gege bi alaye awon ore Tunde, won lati ile iwe ni Tunde pelu awon ore won kan ti n bo nigba ti awon olopa kan ti won maa n gba egunje kaakiri ti won si maa n yo agbegbe won lenu fi gbe ibon fun Tunde laise wi pe boya o n ba eniyan ja tabi wu iwa arufin kankan.,

Awon ore Tunde ti ke gbajari si awon ajafeto omoniyan lati ran won lowo ati wi pe won ti fesun kan asoju ile Naijeria ni ilu Malaysia, Anbasado BELLO SHEHU RINGIM gege bi eni ti ko koju osuwon lati soju omo Naijeria ni ilu naa,


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment