Smiley face

Awon Eniyan N Fi Oju Oniranu Wo Sisi Noosi To Dije Fun Omidan Tatto Ilu UK

Noosi Claire O'Sullivan to dije lati kopa ninu idije Omidan Tatto ti ilu UK eleyii ti won pe akori re ni Liverpool Tattoo Convention ti fi ero re han nipa oju ti awon eniyan fi n wo o pelu tatto to ya sara pelu orisii ise to yan laayo eleyii ti opolopo gba wi pe ko ba oju mu rara.
 
O ni bi oun tile ya tattoo sara, sibesibe oun kii se 'omo igboro' ati wi pe eniyan rere ni oun n se. O ni ti awon eniyan ba kan oun lenu ise, iyalenu ni o maa je fun won wi pe eni ti n se iru ise oun le dara to tobi bi eleyii sara.
 
"Oge lasan ni mo ka si, o si je ohun to fun mi ni idunnu. Eleyii ko si ni ohunkohun se pelu omoluabi ti mo je lawujo" Noosi Claire
 
Noosi Claire O'Sullivan ti yege lati kopa ninu asekagba idije naa nibi ti yoo ti maa figagbaga pelu awon oludije mesa-an ti won jo n du tani-yoo-je Omidan Tattoo ti Ilu UK.
 
Sugbon sa, ti a ba ni ka fi oju mii wo, nje ohun to buru wa ninu ki noosi ya iru tatto bayii sara?
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment