Smiley face

Pastor Nick Ti O Lowo Ti O Lese Ti Ni Iyawo Pelu Omo

Aropin ni ti eniyan, kadara eda wa lowo Olorun oba ko si gbagbe eniboodi rara. Ajinyinrere Nick Vujicic ti won bi gege bi eni ti o lapa ti o lese ni Eduamre ti fi adun si igbesi aye re nipa orekelewa obirin pelu omo rere ti oba Yaradu fi da lola.
 

Igba Nick Vujicic wa ni eni odun mewa, o gbiyanju lati pa ara re sugbon nigba to ya o bere si n lo ipo ailera re lati waasu igbagbo, isipaya ati oro itunnu kari aye.
 
Opolopo waasu re naa lo maa n da lori wi pe o ni idi pataki ti Olorun fi seda koowa ati wi pe ipokipo ti eda ba ba ara re laye ko maa fi ope fun Oba mimo ko si maa dunnu lai ba okan je rara.

Nick Vujicic, eni odun mokanlelogbon pade ni aya rere ti oruko re n je Kanae ni odun 2008, awon mejeeji si so yigi niwaju Oluwa ni odun 2012. Oosa oke dunnu si igbeyawo won lo ba fun won ni omo okunrin lantilanti ti oruko re n je Kiyoshi.

Awon ebi alayo yii wa ni Hawaii lowolowo bayii nibi won ti gba isimi pelu faaji to leku.


' Egan mi ti dogo, Edumare ti pabi da so ibi di ire fun mi. Ayo mi kun, inu mi si dun koja bikiafu.' Pastor Nick

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment