Smiley face

Ile Ounje Igbalode Ti Won Ko Si Isale Omi Okun

Ile itura Conrad Maldives Hotel lagbo wi pe won ti ko ile ounje igbalode eleyii to je akoko iru re ti won yoo ko si isale omi okun fun igbadun awon onibara won.


Gege bi akojopo Olayemi Oniroyin Agbaye, owo ina ijoko jeun eniyan kan soso to nnkan bi egberun mokanlelaadota owo naira ile wa (£190/N51,000)

Sebi awon Yoruba loni obe to dun, owo lo pa. Owo ti won fi pari ile ounje igbalode naa n lo si nnkan bi milionu mokanlelogorin nisiro owo naira ilu Naijeria (N81 million).

Erekusu Rangali to wa ni orileede Maldives ni ile itura yii wa. Ile itura kan naa yii si ti gba ami eye ile itura to gbayi ju lo nigbogbo agbaye fun igba meji otooto.

Orileede Maldives daduro si aarin omi okun to wa laaarin Indian Ocean ati Arabian Sea.

Ojo kerindinlogbon osu keje odun 1965 ni won gba ominira lowo ijoba Biritiko (July26 1965). Esin Islam si je gbajugbaja esin ni ilu Maldives. Ilu yii ko tobi rara, apapo iye awon eniyan ti won gbe ni odindin orileede Maldives won ko to ilaji awon eniyan ti n mbe l'Eko Adele. Bee owo tabua ti n wole fun won lodoodun eleyii to koja ojo ori won gege bi orileede.

Olayemi mo fe dake nipa ilu kekere ti n se ohun nla ti won pe ni Maldives. Ki Edua ko dakun, ko ba wa da ogo Nigeria pada.

E ku imusile ise ola!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment