Ijamba ina nla kan sele lana ni oja Daleko to wa ni Ijoba Ibile Mushin ni ilu Eko. Awon soobu ile itaja bi ogofa (120) lo jona wuruwuru nigba ti dukia to to milionu lona milionu si poora lojiji.
Nnkan bi ago meji ku iseju mewaa ni ijamba ina naa bere loganjo oru ni iso awon ti won n ta ororo ko to di wi pe ina naa n fo kiri oja bi obo langido.
Awon olode ti won so oja naa ni won sare lo ji awon aradugbo wi pe ina n jo.
Gbogbo akitiyan awon eniyan yii lati pa ina naa lo jasi pabo ki awon osise panapana Ipinle Eko to de pelu oko omi panapana.
Ogbeni Rasaq Fadipe to je oga awon panapana Ipinle Eko jeri si isele naa. E gbo bi won ti wi:
"Immediately I received the alert, I deployed three water tankers to the scene.
"We would have been able to put out the fire few minutes after our arrival and more property would have been saved.
But the fire was fuelled by the vegetable oil products stocked in the shops."
Ina monamona lagbo wi pe o sokunfa isele ijamba ina buruku naa. O si gba awon panapana ni nnkan bi wakati kan ki won to segun ina ti n jo witiwiti bi ina orun apaadi.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment