Smiley face

Boko Haram Se Abewo Si Ilu Kano Pelu Ado Iku Oloro

Nnkan bi ago mesan-an ale ana(18/5/14) ni ado iku kan eleyii ti won gbe sinu moto dun ni agbegbe Sabo Gari to wa ni ilu kano.

Gege bi iroyin ti a gbo se fi to wa leti, awon eniyan bi marun-un o kere tan ni won ba isele naa lo ati eni to gbe ado iku naa wa.

Isele yii ni opolopo gba wi pe o seese ko je awon omo alakatakiti esin Islam ti a mo si Boko Haram lo wa nidi isele naa.

Komisanna Ilu Kano, Adelere Shinaba ti jeri si isele buruku naa sugbon oro re ni wi pe o ti yaju fun awon eniyan lati gba wi pe Boko Haram lo wa nidi isele naa niwon igba ti ise iwadii ko ti bere lati mo tani amokunseka.

Ti e ko ba gbagbe, losu keta odun to koja, awon eniyan bi merinlelogun ni won sagbako ado iku oloro Boko Haram ni agbegbe Sabo Gari yii kan naa. Bee si ni opolopo awon eniyan ti won wa ni agbegbe Sabo Gari yii ni won je ajoji lati Guusu eleyii ti pupo ninu won je omo leyin Jesu.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment