Awon Yooba bo, won ni olotito eniyan ni ota araye, eni ti n paro ni awon eniyan n pe ni eni rere. Sebi oro owo epo robi ti won jiko ni won fi gba ise lowo Sanusi ki Oba Oluwa to fi ipo oba da lola. Sanusi de ile ola tan, won tun n binu eni Edua n gbe nija.
Otito oro naa ni Edmund Obilo to je osise ile ise Splash FM ti ilu Ibadan so fun araye nipa owo Ipinle Oyo ti Gomina Abiola Ajimobi n pin pelu Alaafin Oyo. E le ka ekunrere iroyin naa [NIBI].
Lori oro yii ni won se ni ki okunrin sorosoro naa lo joko sile na. Iwe Lo-Joko-Sile ti won fun Edmund Obilo ni a gbo wi pe ase re wa lati odo Gomina eleyii to se apejuwe okunrin naa gege bi omorogun eleyii ti ko mo ise ko to fi tori bo omi gbigbona.
Lori oro yii ni won se ni ki okunrin sorosoro naa lo joko sile na. Iwe Lo-Joko-Sile ti won fun Edmund Obilo ni a gbo wi pe ase re wa lati odo Gomina eleyii to se apejuwe okunrin naa gege bi omorogun eleyii ti ko mo ise ko to fi tori bo omi gbigbona.
Sugbon okiki oro naa to kan kiri aye ko je ki okan ijoba Ipinle Oyo ati awon alase ile ise Splash FM bale mo eleyii lo n mu won wa ona ati daso bo oro naa mole.
Gege bi oro okan lara osise Splash FM lori eto Tifuntedo, Folake Otuyelu, obirin naa tako iroyin naa wi pe iro ni ati wi pe ko si ohun to jo mo bee rara. Sugbon oro naa ti pada beyin yo, akara ti tu sepo. E gbo ohun ti Edmund Obilo wi nipa isele naa:
" I am aware that some politicians are not happy with the way do treat issues on my programme and i am only doing my job, I have no problem with anybody and nobody ever told me that I offended him or her with my style of presentation,some people actually against me and they wanted me dismissed but i am only on suspension and my suspension has expiry time .' - Edmund Obilo
Leta ti won fun okunrin naa ni yii lori isele to waye.
![]() |
Leta Lo-Joko-Sile |
Pelu igbese Ijoba Ipinle Oyo ati awon alase Splash FM, nje a le gba wi pe lotito ni Oba Lamidi ati Gomina Ajimobi n se apapin lori owo Ipinle Oyo abi aheso lasan ni gege bi Folake Otuyelu se so?
0 comments:
Post a Comment