![]() |
Igboho ati Ayefele |
Sunday Adeyemo ti gbogbo eniyan mo si Igboho Sunday (oun naa ni won tun pe ni Igboho Oosa) ki i se eni ti won n se apejuwe re rara. Orisiirisii aheso oro lo n lo nigboro nipa iru eniyan ti okunrin yii je. Opolopo awon eniyan gba wi pe alagbara eniyan ni i se, eleyii ti ti ko si ariyanjiyan nipa wi pe se beeni tabi beeko- konfaamu ogun mbe lowo Igboho.
Sugbon ohun ti n ko awon eniyan lominu ni wi pe bawo ni Igboho se n lo agbara re to ni. Awon kan gba wi pe janduku paraku ni Igboho. Nigba ti awon kan so wi pe akoya ni Sunday omo Adeyemo ki i se omo ita rara . Awon kan tile maa n pe ni ojise Olorun oga ogo lati orun wa saye nitori won gba wi pe akanda eniyan ni i se.
A ko le fi idi aheso yii mule bayii nipa wi pe bawo ni Igboho se n lo agbara to ni lawujo. Boya ero awon eniyan nipa Igboho jeyo nipa ipa ti Igboho ko nigba ogun to waye laaarin Ife ati Modakeke eleyii ti awon eniyan so wi pe Igboho wa lara awon ajagunta ti won be lowe.
Yato si eleyii, Igboho tun un se atileyin tabi akoya fun awon oloselu alagbara. Sunday ti sise pelu awon kan ninu egbe PDP tele ri ko to wa fori sabe Senator Rasheed Ladoja. Boya awon ona ti Igboho n rin yii lo je ki awon eniyan maa foju janduku wo Igboho.
Sugbon sa, ti Sunday Adeyemo ba je janduku ba wo lo se wa je wi pe awon eniyan aponle lawujo n ba a sore? Ore awon wooli nlanla ni Sunday Igboho, awon Alfa nla ti Olorun gba fun fi enu rere pe Sunday. Mo ti le ranti wi pe Alfa Muyideen Bello fun Sunday Igboho loruko musulumi, Saliu lojo to se adura ile re tuntun to si ni ilu Ibadan.
Ti Sunday ba je janduku se awon eniyan yii le maa ba jeun papo bi? Abi awon eniyan mimo yii ni won ko mo wi pe janduku ni Igboho Oosa?
Abi awon iwa ibi ti a n gbo nipa Sunday Igboho ki i se oun gan-an lo wa nidi iwa naa to je wi pe awon kan ni won fi oruko re da igboro ru ?
![]() |
Sunday ni eni kinni lati apa otun nibi ayeye isinku awon obi Kola Oootu to waye ni kopekope yii ni ilu Ibadan
|
Olayemi Oniroyin, iwadii mi ti pari nipa Sunday Adeyemo (Igboho Oosa), ki n ka te jade fun yin nikan lo ku bayii.
Iru eniyan wo ni Sunday Igboho?
Ibo ni Sunday Igboho ti ri agbara to n lo?
Bawo ni agbara Sunday Igboho se to?
Awon itu wo ni Sunday Igboho ti pa seyin?
Okiki, agbara ati ola Sunday Igboho.
Awon idahun si ibeere yii ni e o maa ri ninu apa keji apileko mi ti mo pe ni 'TANI SUNDAY IGBOHO?'
Sugbon awon Yoruba ni a ki i toju onika mesan-an kaa. Mo fe toro iyanda lowo awon eniyan ti won sun mo Sunday Igboho. Ti won ba ti ni kosi giri a je wi pe e o ka iroyin lekunrere eleyii ti mo pe akole re ni TANI SUNDAY IGBOHO?.
Iru eniyan wo ni Sunday Igboho?
Ibo ni Sunday Igboho ti ri agbara to n lo?
Bawo ni agbara Sunday Igboho se to?
Awon itu wo ni Sunday Igboho ti pa seyin?
Okiki, agbara ati ola Sunday Igboho.
Awon idahun si ibeere yii ni e o maa ri ninu apa keji apileko mi ti mo pe ni 'TANI SUNDAY IGBOHO?'
Sugbon awon Yoruba ni a ki i toju onika mesan-an kaa. Mo fe toro iyanda lowo awon eniyan ti won sun mo Sunday Igboho. Ti won ba ti ni kosi giri a je wi pe e o ka iroyin lekunrere eleyii ti mo pe akole re ni TANI SUNDAY IGBOHO?.
Iwadi nla lele yii o. Oga Olayemi, Iwadi n la gan an nii......... Olorun olojo oni yoo maa wa pelu yin ni Oruko Jesu.
ReplyDeleteAmin o. Thanks
ReplyDeleteE ku ise. Sugbon maa royin kee se jeje pelu Sunday ooooo. Nice job.
ReplyDelete