Akon ti se afihan yara agbara ile orin re tuntun eleyii to kun fun awon irinse igbalode lati ba igba mu. O jo bi eni wi pe eleyii wa lara eto lati gbe àwo orin re tuntun jade eleyii ti ise n lo lowo lori re.
Akole ti AKON gbe le aworan naa ni yii;
'In the lab cooking up that dinner for the Holidays!! # Defend'
Yato si eleyii, agbaoje olorin naa tun se afihan aworan re tuntun pelu Wizkid. A ko le so pato nipa eleyii, sugbon o seese ko je wi pe won sise kan papo ni.
Eni a n gbe iyawo bo wa ba, awon Yoruba ni kii gbe ori iganna woran. Bope boya ohun ti awon mejeeji n se ni koro yoo han si gbangba.
Ninu iroyin mii, AKON se alaye igbe aye re gege bi iyanu. E le ka iroyin naa nibi: http://olayemioniroyin.blogspot.com/2013/04/iyanu-ni-igbe-aye-mi-akon.html
Olayemi Oniroyin loruko mi, e ku asiko yii.
0 comments:
Post a Comment