Smiley face

A Ku Ori Ire o: Won Ti Ri Ogun Iwosan Ebola Ni Ilu Canada

Awon onimo isegun ilu Canada ti ri ona abayo nipa ogun to le wo arun kokoro Ebola ti n yo iwo-oorun Afirika lenu eleyii to ti da emi opolopo eniyan legbodo.

Bi o tile je wi pe ara eranko ni won ti koko gbiyanju ise ogun oyinbo naa eleyii to sise to si mu ebola kuro lara eranko ti won loo fun. Won ko ti lo ni ara eniyan, sugbon igbagbo won ni wi pe o ye ko le sise fun omo eniyan.

Nibayii, awon alase ilu Canada ti setan lati ko awon ogun naa fun ajo World Health Organization fun iwulo awon eniyan ti won ni Ebola lara.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment