Oni ojo Satide mi o rode lo. Ore mi kan n se igbeyawo lonii ni Ilesha sugbon ilu Abuja ni mo wa lowolowo bayii.
Baalu ni mi o ba gbe de ilu Ibadan ka ni sen-inji die wa lowo mi ni. Mo gba kamu, mo ya n wo fiimu lori Africa Magic Yoruba jeje.
Ero foonu mi dun:
Emi: helooo
Alejo: Heloo! E joo, se Olayemi Oniroyin ni mi n ba soro yen?
Emi: A wa ni o. Eye meji kii j'asa.
Alejo: Good! Ham..ham.. T. Bebe ni oruko temi o. A maa n gbadun yin gidi gan-an ni ke.
Emi: E se pupo.
Alejo: E joo, mo fe kee ma promote wa ni. Se e ri, awa ni won pe ni Omoge Onidodo, group ni wa o. Ti e ba wo inu Inbox yin, e ma ri awon foto omo egbe wa ti mo ti send si yin.
[Bi omoge naa se n soro bee ni mo se 'Okay...Okay'. Awon alaye re ko tile ye mi daadaa]
Emi: E joo, iru promotion wo gan-an le fe? Awon alaye yin ko ti ye mi daadaa.
Alejo: E ma maa gbe wa laruge, shocase wa, e ma maa ko articles orisiirisii nipa wa. Se nnkan ti mi n so ti ye yin?
Emi: E joo, nnkan ti e n so ko ti ye mi o. Ise wo gan-an le n se? Hello se n gbo mi....Hellooo [Ila ti ja kuro loju opo].
Olorun ma wa saanu mi o. Abi awon wo ni Omoge Onidodo? Se dodo Ikire ni won ta ni abi e wo?
Mo lo wo inu apo iwe ifiranse mi. Mo ba awon foto orisiirisii looto, sugbon aworan ti mo ri ko jo ti awon omo ti won ta dodo loju titi.
Olorun ma je n sise gba o, abi iru awon omo onidodo wo leyii?
Igba to pe die, nomba to pe mi tun pada wole.
Alejo: Oniroyin, e maa binu o. Network lo cut line yen. Mi ma pe yin pada se e gbo? Ke e ni nice da.
Mo ti gbase loco, temi ti ba mi bayii. Nje eyin mo awon ti won je Omoge Onidodo?
0 comments:
Post a Comment