Ile ejo to gaju ti Ipinle Ekiti ni wahala nla ti sele lana ojo Aje (22-09-14) nigba ti awon omo aye kan bi ogorun ya wo kootu ti won ti n se igbejo nipa Gomina tuntun ti won dibo yan ni Ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose nipa esun wi pe ko pegede lati dije ninu eto idibo gomina to waye lojo kokanlelogun osu kefa odun yii.
Igba ti wahala ta n so yii beere, ti gobe jawo inu kootu lojiji, onidajo Olusegun Ogunyemi gan-an ko duro ko gbogbo faili ejo re to fi gba eyin ile salo. Awon agbejoro gan-an ko duro mu fila to jabo. Awon eniyan ti ko ni ayeta lara n pariwo "eje Jesu gbamila". Oro di boolo o yago lona. Taa ni nje omo akuwarapa niwaju omo akuyan-anyan ti n sere gele? Sebi eni ija o ba ni i pe ara re lokunrin.
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment