Smiley face

Abadofin Ati Yo Aare Jonathan Loye Ti De Iwaju Ile Igbimo Asofin Agba

Iroyin tuntun to jade lojo Aje, Monde to koja yii ni wi pe awon omo ile igbimo asofin kan ti gbe abadofin kan si iwaju ile lati yo Aare Goodluck Jonathan loye gege Aare Ile Nigeria, Ilu to kun fun wara ati oyin latari bi awon olopa alaso dudu se ti ilekun ile igbimo asofin abuja pa lose to koja mo Aminu Tambuwal.

Isele yii ni won lo ni owo Jonathan ninu eleyii to si lodi sofin pupo ju. Sebi won ni ti ina ko ba lawo kii goke odo. Ti ko ba si sohun to se ese, ese kii se lasan. Eniyan lo wa nidi oro, loro fi n ke. Eegun ti n jo lori omi ni, onilu re wa nisale odo.

Bakan naa ni a tun gbo wi pe won ti fi iwe pe oga olopa ile yii patapata lati foju han ni ile igbimo asofin lati wa so tenu re fun gbogbo ile nipa ohun to ri lobe to fi waru sowo.

Oni ojo Isegun (25-11-14) ni Ile yoo tun maa se agbeyewo abadofin naa.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment