Smiley face

Aminu Waziri Tambuwal: Bi Ina Ko Ba Tan Laso Eje Kii Tan Leekanna

Sebi awon Yoruba ti ni bi ina ko tan laso eje kii tan leekanna. Iduro o si, ibere ko si fun eni o si gbodo mi. Lori oro Tambuwal to je olori ile igbimo asoju-sofin, alaga egbe PDP lapapo, Alaaji Adamu Mu'azu ti setan lati se ipade po lonii pelu awon omo egbe PDP ti won wa nile lori wi pe bawo ni won se fe yo Tanbuwal danu latari bo se fi egbe PDP sile bo sinu APC.

E maa si gbagbe wi pe lojo Eti to koja yii, Tambuwal pelu awon omo egbe APC ti won je omo ile bi ogota ti lo pejo ni kootu to ga ju lo latari bi ile ise olopa Naijeria se ko awon osise alaabo Tambuwal kuro leyin re bi igba eye asa gbe oromadie kuro leyin iya re.

Wayio, awon onwoye nipa oro oselu kan so wi pe lotito ni ofin so wi pe omo ile igbimo asofin to ba fi egbe re sile bo sinu egbe mii ni akoko iyan sipo re gbodo fi ile sile niwon igba to je wi pe egbe re tele ko ba pin si meji latari ikun sinu. Won ni sugbon sa, ile ise olopa ko ti i leto lati gbe iru igbese ti won gbe.

Gege bi amofin Femi Falana se so, o ni ko si ohun to le yo olori ile ju ti ida meji ile ba joko fowo si wi pe ki won se bee lo.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment