Smiley face

Iroyin Nipa Fidio Omoodo Uganda To Fe Pa Omo Odun Kan Aabo To N Toju Ninu Ile

Laipe yii ni fidio ibanuje kan jade sori ero ayelukara eleyii to n se afihan bi omoodo, eni odun mejilelogun (22) kan se fi iya ajekudorogbo je omo kekere kan ti ojo ori re ko ju odun kan aabo lo eleyii to n toju ninu ile.

Kampala to je olu ilu Uganda ni isele naa ti sele nibi ti won ti gba Jolly Tumuhirwe gege bi olutoju Arnella, omo odun kan aabo.

Nibayii, owo awon olopa ti te omobirin naa. Ile ejo Nakawa Magistrates si ti fi onte luu wi pe ki won lo fi si ahamo titi ojo kejo osu kejila (December 8) odun 2014 nigba ti won yoo maa gbejo re.

Ki ile ejo to pase ki won lo fi si ahamo, won se ayewo opolo fun omoodo naa boya oni arun opolo ni. Abajade ayewo si fi ye won wi pe opolo re pe perepere.

Eyi ni alaye Erick Kamanzi to je baba omo ti omoodo naa se sakasaka:

"Gbogbo igba ni omo naa kii le rin daada ti a ba de lati ibi ise. Tabi ki omo naa maa ke ti a ba fi owo kan awon ibi kan lara re. Eyi lo mu mi so fidio CCTV si inu ile eleyii to pamo fun omoodo naa ki n le mo nipa ohun ti n sele leyin mi, nigba ti emi ati aya mi ko ba si nile. Ibanuje nla lo je fun mi nigba ti mo ye ohun ti ero CCTV naa ka pamo sinu."

Onidajo Nakawa Magistrates fi idunnu re han pelu bi awon obi omo naa ko se te ofin loju nipa sise idajo lati owo ara won. Gege bi oro onidajo, oni ko si abiamo ti won yoo se omo re bayii ti ko ni fe si iwa wu.

Gege bi iwadi olayemioniroyin.com, ojo merindinlogbon (26 days) pere ni omoodo naa fi sise ki won to fura wi pe iranse esu pombele ni awon gba sile lati maa se itoju omo won.

Iya omo naa ti gbe omo re lo si osibitu, ara si ti n bale daada. Sugbon ko daju wi pe awon ebi yii yoo tun pada gba omoodo kankan mo lati ma se itoju omo won.

Olayemi Oniroyin, maa duro nibi. O tan lenu lasan ni, o tun ku sikun. Omo eniyan lo tu ito funfun jade lenu ti won fi dudu sinu. Ojulari! Eniyan ti n banije-banimu le je ota eni. Sasa eniyan nii feni leyin taa ba si nile, terutomo nii feni loju eni. Eniyan won, ara aye eniyan soro. E fura!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment