Smiley face

"OMO ADELUGBA LO!" - Olanrewaju Adelusi Opele Oro

OMO ADELUGBA LO!

Ohun Ipaya Ati Iyalenu Nla Gbaa Lo Je Fun Mi Nigba Ti Mo Gbo Nipa Ikuu Baba LEsa-Oke Nni, Ojogbonfeyinti (Emeritus Professor) Dapo Adelugba! Ki I Kuku Se Wi Pe Mo Mo Baba Naa Ni Amodunju To Bee, Sugbon Ki Baba Yii O Too Ta Atapinse Pelu Ile Eko Giga YuniFasiti Ibadan Lo Si YuniFasiti Ti O Wa Ni Zaria, Ni Nnkan Bi Odun Mejila Si Metala Seyin, Mo Lanfaani Lati Se Alabaapadee Won.

Nnkan Ti Mo Si Le Ri Toka Si Nipa Baba Naa Ni Pe, Won Je Oloyaya Eeyan... Awada Po O Jare! Ohun Ti O Si Maa N Je Iyalenu Fun Mi Nigba Naa, Ti Emi A Maa Ro Lokan Mi Pelu Ibeere-pesije (Rhetorical Question) Ni Wi Pe, "Nje Eeyan Ha Le So Pe Oluko Ni Eni Ti O N Ba Awon Akekoo Da Apara Bayii?"
Ka Soro, Ka Yan An, Mo Ri Iwa Omoluwabi Ati Eniyan Rere Lara Baba Naa! Bee Ni... Pelu Iwonba Oro Ti Mo Ti Gbo Nipa Won Latenu Awon Akekoo Imo Isere Tiata Ti O Wa Ninu Ogba Fasiti Ibadan.

Bi Omo Eni Ba Daa, Ko To Fun Olododo Eeyan Lati Fi Iyin Iru Omo Bee Sabe Ahon So..

Ohun Ti O Je Kayeefi Ati Ipaya Fun Mi Nipa Ikuu Baba Ni Pe, Ni Osan Ojo Isinmi (Sunday) Ti Baba Terigbaso Gan-an Ni Mo Si Sese Kan Si Eeyan Wa Kan (Tolu Fagbure) Pe Boya O Le Ba Mi Ri Iwee "That Scoundrel Suberu", Ti Baba Ko. Eemeji Otooto Ni Mo Ti Wo Ere Naa Lori Itage, Ni Fasiti Ibadan Tia-n-tia Si Ni..

Olasunkanmi Adebayo (Ogaa Mi Ni O) Lo Se Suberu Nigba Naa, Iyen Nigba Akoko Ti N Oo Wo O.

Nigba Ti O Se, Omowe Sola Fosudo Naa Tun Ko Awon Omo Won Wa Lati LASU (Lagos State University), Niluu Eko, Tori Bi N O Ba Shi I, Awon Ni Won Je Olori Eka Imo Isere Ti N Be Nibe (LASU) Nigba Naa. Awon Akekoo Imo Isere Ti LASU Naa Gbiyanju Pupo! Won Fakoyo! Won Peregede! Won Fi Gbooro Jeka! Ise Ni Won Se O Jare-Won Gbounje Fegbe Koda, Won Tun Roju Duro Gbawo Bo; Ani Won Gba Awo Naa Tan, Won Tun Fo O Ko Mo Tonitoni!

Sugbon Se Ki A Ma Tan Ara Wa Je, Awon Akekoo Imo Isere Tiata Fasiti Ibadan Lo Gba Olu Lowoo Won O, Egan Ni 'Hee' Bi Oruko Baale Ibikan! Kii Kuku Se Wi Pe Won Dije, Ifoju-inu-wo Temi Ni Mo Fi Se Idajo..

Eyin Naa Ti Ro Pe Yoo Ri? Araba Ma Ni Baba O, Eni A Ba Laba Ni Baba! Amo Mo Shi N Wa Iwe Naa O..

Labee Gbogbo Bo Ti Le Wu Ko Ri, Iku Ti Pagbe Bi Alaileedaro; O Paluko Bi Alaileekosun; Iku Pa Lekeleke Bi Eyi Ti O Lee Kun Efun!

Iku Pagilinti Onilu Booke. Opalamba Oti Eebo Ti Fo, Onigbanso Kan O Tie Ri I So! A O Ti Soro Alumuntu Ka Yo Ti Jinnijinni Eru Ti I Da Baayan? Eni To Waye Aiku, Konitohun O Bo Si Gbangba Ko Waa Wi; Eni Ti Ita Baba Re O Ni Digboro Ko Wa Fo ni Gbagede O Jare..

Gbogbo Wa Patapata La Ti Dagbada Iku, Lojo Ta A Ba Ni Ode Ati Lo Salakeji La Oo Wo Ewu Aremabo! Ki Lo Gbele Aye Se, Wi Si Mi Leti.. Ki Nile Aye Ti Gbe O Se, Fo Si Mi Lodo Ikun.

Ki La Mu Waye Ta O Fe Fi Sile Ba A Ba N Lo?

Alumuntu Riga Nkoowa... Gbogbo Wa La Dagbada Iku O! Pelepele To Wa Lowo.. Peleputu Dowoo Gbogbo Wa!

Bi Oladapo Ni Baba, Bi Adedapo Ni, Emi O Ma Tie Lee So O.. Ohun Ti Mo Mo, To Si Tun Da Mi Loju Saka Ni Wi Pe, OJOGBONFEYINTI 'DAPO ADELUGBA Ti Lo Ree Feyin Ti Patapata, Baba Ti Ki Aye Pe O Digba O Se!

Toh!

Lati owo: Olanrewaju Adelusi (Opele Oro)

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment